Home / Art / Àṣà Oòduà / Abiola Ajimobi sùn un re
abiola ajimobi

Abiola Ajimobi sùn un re

Ikú pàgbẹ̀ àṣírí aláró tú.
Ikú pàlùkò àbùkù kará ìkosùn.
Ọrùn má kánjú, gbogbo wa la dágbádá ikú.
Ìgbà átàsìkò ẹ̀dá ló só kùnkùn.
Gíńgín ladáhunṣe tó mewé e re.
Gbogbo wa lòpè nípa àkúnlẹ̀yàn.
Òkú ń sunkú òkú, akáṣọlérí ń sunkú ara a wọn.
Sùn un re oo Àjànàkú ọkọ Florence, Àkànjí ẹ̀rù , mọ́ ṣẹ̀rù baya, bọmọ tó o fi sáyé lọ.
Má ṣẹ̀rù bàlú, sun- un-run ìgbẹ̀yìn pàdé Allah nídẹ̀ra .

Àkànjí ẹ̀rù Sheeeeuuu,ibi o fàdàgbá ayé rọ̀ sí, ọmọ ni yóó lòyókú.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

nigerian police

Wọ́n gbẹ̀mí olórí ẹgbẹ́ jàǹdùkú ”One Million Boys” n’Ìbàdàn

Wọ́n gbẹ̀mí olórí ẹgbẹ́ jàǹdùkú ”One Million Boys” n’Ìbàdàn Ọmọ ò fìgbàkan láyọ̀lé, ẹni ọmọ dúró sin onítọ̀ùn ló bímọ. Gbogbo ẹni tó bá bí jàǹdùkú, olè, gbàjùẹ, kọ̀lọ̀rànsí l’ọ́mọ, kónítọ̀ùn ó má tíì yọ̀ láyọ̀jù nítorí pé *ÀBÍKÚ ÀGBÀ* ló bí.Ó díá fún bí wọ́n ṣe ṣekúpa olórí ”Onẹ Million Boys”, Biola Ebila. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọròyìn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú. Lágbègbè Olómi nílùú Ìbàdàn ni a gbọ́ pé ọwọ́ pálábá ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ olórí ...