Home / Art / Àṣà Oòduà / Oríkì Ẹ̀rìn Òsun

Oríkì Ẹ̀rìn Òsun

Ẹ̀rìn moje ọmọ saaja,
Ọmọ eléwé ladogba òróró maro,
Ẹ̀rìn wagunwagun
Ewá w’Ẹ̀rìn logun eniti yíò wá Ẹ̀rìn logun kowa àpò ide kolowa ọfà,
Bàbá kòníbon ajíperin nílé,
karo ń lè mọ wọn lójú ogun ẹni Ẹ̀rìn mọ jẹ́ ta l’ọfà tikoku titi ọjọ́ ale afori wowe lobisu Ẹ̀rìn mọ jẹ́ lọmọ
Igi kan igi kan toya dina l’Ẹ̀rìn,
Nipopo olowe koje ki ọmọ elẸ̀rìn,
oroko kòjé kí Ìwòfà elẸ̀rìn orodò,
Ènìyàn mélòó nani yio gegi oro naa,
Olowe wọn ní kí wọn wá,
Abuké méje,
Arọ méje,
Adití méje,
Abuké ngegi lọ apá kan ń dùn karara,
Apá kan ń dùn kororo,
kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi,
oro naa ja nipopo olowe arara ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo,
kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi arara base dùn le lomori wogbo, Owadi elékẹta ototo adití tí kò gbó t’ayé tí kò gbó tọrùn sebi oun logegi ọ̀rọ̀ náà nipopo olowe,
kinni wọn ba nínú igi wọn ba osahin wọn ba ọkà bàbà ìbọn oje eku eyan tokanrin nílé tápà nílé ọmọ afowuro dáná kúlíkúlí….
Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí ìlú Ẹ̀rìn Òsun pé oooo

http://edeyorubatiorewa.blogspot.co.uk/2016/08/oriki-erin-osun.html

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Aregbesola

Aregbesola Should Admit He Failed In Osun – PDP

The Osun State chapter of the Peoples Democratic Party has advised the immediate past governor of the state, Mr Rauf Aregbesola, to admit he failed in his tenure in the state. The party in a statement on Sunday signed by Sunday Bisi, its Publicity Secretary, in reaction to the virtual colloquium held to mark Aregbesola’s 63rd birthday, said the measured assets on the ground in the state were far below the quantum of the loans accessed by the former governor. ...