Home / Art / Àṣà Oòduà / Awon Tia N’Ibadan

Awon Tia N’Ibadan

Ibadan mesi Ogo,
Nile Oluyole,
Ilu Ogunmola,
Olodogbo keri loju ogun,
Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya,
Ilu Ajayi o gbori Efon se filafila.
Ilu Latosa Aare-ona kakanfo,
Ibadan Omo ajoro sun,
Omo a je Igbin yoo,
Fi ikarahun fo ri mu,
Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni,
Eyi too ja aladuugbo gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun.
Ibadan Kure!
Ibadan beere ki o to wo o,
Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji.
Eleyele lomi ti teru-tomo n mu ni Layipo.
Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan.
A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
OMO IBADAN KI NI SOO YIN??
SO N SUO SA????
A nfi akoko yi kede fun gbogbo Omo Yoruba Atata ni Ilu Ibadan ati Agbegbe re wipe Ipade egbe Omo Yoruba Atata eka ti ilu Ibadan yoo waye ni ojo abameta ojo ikerindinlogun osu igbe ti a wa yi.
OJO IPADE;-OJO IKERINDINLOGUN OSU IGBE.
IBI IPADE;-ILE ITURA BEMBO
AKOKO IPADE;-AGO MEJI OSAN
A nro gbogbo Omo Yoruba Atata pata ti o wa ni ilu Ibadan ati ayika re lati gbiyanju kopa ninu ipade yi, fun ilosiwaju ati igbasoke egbe Omo Yoruba Atata kari aye.
IJUWE ONA SI IBI IPADE;- Lati Ibikibi ni igboro ibadan, e wo oko ti nlo si APATA, ki e bo sile ni ILE Epo OANDO. Lati ile epo yi, e rin siwaju die, ki e ya si inu oja. Lati inu oja, e o gun Alupupu (Okada) tabi Keke Maruwa ti nlo si ILE ITURA BEMBO. E sokale ni ile itura yi ki e si wole kanle, e ti debi ipade niyi.
Fun alaye lekun rere lori Ijuwe Ona ati nkan miran e pe awon onka ibanisoro wonyi;-

KABIYESI;-08027840877
Alagba SOMADE OLAWALE AJAO;-08033982750, 09091054057.
Adura wa ni wipe Olodumare yoo ba wa di ojo na mu, ohun ti a ko ro ki yoo ba eyi ti a nro je lase Edumare. A ro gbogbo Olugbe ibadan ati agbegbe re ki a tuyaya tuyaya wa sibi ipade yi se gbogbo wa ni a kuku mo wipe ibadan kii gbeyin nibi gbogbo? Sugbon enu lasan ko ni won fi nse o! O di ojo na ojo ire ki a to mo boya oga nibadan looto.
Baami Somade Olawale Ajao o dowo yin o, Iya Adinni mi Alhaja Adetunji Adenike J o dowo yin, Maami Orimadegun Tunmise Iya’badan, eyin da? Oluko mi Olùkó Èdè Yorùbá Arb, e ku igbaradi, Omidan Falade Opeyemi Cecilia e ku imurasile o, maami Alimat Aina Ismail Fasasi o dowo yin, Alagba Adekunle Soliu o dowo eyin agbagba, Alagba Azeez Wasiu Kobewude e ku igbaradi, omobabinrin Princess Oluwakemi Morenikeji Idowu. E ku igbaradi. Alagba Olanase Hammed Olamilekan e ku imurasile.
Gbogbo Ebi Omo Yoruba Atata nibadan e ku igbaradai ooo

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

ibara

5 residents, 5 attackers killed, vehicles, petrol station razed as killer Fulani herdsmen invade Igangan

No fewer than 10 persons have been reportedly killed by suspected killer Fulani herdsmen at Igangan, in Ibarapa North Local Government Area of Oyo State. Residents told our correspondent that the attack started at around midnight on Sunday. The assailants who were said to be many reportedly shot dead five residents and security agents who were said to have rushed to the town also killed five among the attackers. A truck loaded with cassava flour and some cars were said ...