Home / Art / Àṣà Oòduà / Odo Iwoyi !
odo

Odo Iwoyi !

A ki gbogbo wa ku ise oni, a si ki wa ku abo sori eto wa eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E dakun e wa nkan fidi le abi ki e fi idi le nkan, ki a le jo gbadun ara wa loni.
Eto wa ti ose yi yoo yato die si awon eyi ti a ti ma n se lati eyin wa, oro kan ni mo mu wa loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a jo gbee yewo, ki olukuluku wa si so oye wa nipa oro yi, ki awa odo iwoyi le kogbon latara oro yi. E maa ba mi kalo;-

Ti a ba se akiesi a o rii wipe igbeyawo awon baba ati iya wa ni aye ojosi maa n pe ju ti aye ode oni lo, bi o tile je wipe ko fere si onirunru ona ti a fi n fi ife han laye ode oni ni igba na, tori emi o ri ojo kan ti baba to bimi lomo gbe maami lo ode sinima tabi lo eti okun, tabi lo ibi igbafe kan lati lo se faaji, sugbon sibe ife ti nbe laarin won ko kere, ti kii ba se iku ti o gba baba mi lowo maami ni, afaimo ti ki baa se ori ara won ni won yoo wa bi mo ti n soro yi.

Awon nkan wonyi wa n se mi ni kayefi tori mo wo ohun ti nsele ni aye ode oni, ikosile laarin oko ati aya wa dohun amuyangan. Awon obinrin kan tie wa ti o je, ero won ni ki won bi omo kan abi meji ki won si di iya idangbe ti won ko si ri ohun ti o buru ninu re. Beeni awon okunrin kan wa toje ero wo ni ki won bi omo meji ki won si daaru pelu iyawo won, ki won si ko awon omo si ile eko ti won yoo ti maa gbe inu ogba ile eko, tabi ki won ko awon omo lo odo mama won, ki won si maa je aye bi o se wuwon. Eyi ti o tie se mi ni kayefi ni ti awon obinrin ti won lokiki tabi ti won ri jaje die, opo ninu won ni kii le duro nile oko fun igba pipe.

Elomiran yoo se igbeyawo aye yoo gbo beeni orun yoo mo, bi won ti se ti orile ede yi ni won yoo tun kori si orile ede miran ti won yoo si na rogurogu owo, sugbon ko ni ya yin lenu wipe leyin osu melokan ni e o ba gbo wipe igbeyawo ojosi ti fori sopon. Ti ko si ni je ibanuje fun won, koda e o tun ri won ninu iwe iroyin ati ero amohunmaworan ti won yoo maa soo ti won yoo si maa fi yangan wipe igbeyawo awon ti dojuru.

Awon oro yi maa n se emi ni kayefi iyen ni mo se ma n bi ara mi ni awon ibeere kan ti nko si ri idaun ti o kunna fun ara mi, idi niyi ti mo se ro wipe boya ki n na oro na sori afefe, ki a jo fi oju sununkun woo, ki eyin ojogbon ati oloye eniyan si ba mi da sii, awon ibeere mi owun ni iwonyi;-

Ibeere mi akoko ree ;-KI NI ASIRI AWON BABA ATI IYA WA NI AYE ATIJO TI WON FI MAA NGBEPO FUN ADOTA ODUN, OGOTA ODUN ATI JUBE LO.
Ibeere Ekeji;- KI NI NSE OKUNFA TI IGBEYAWO OPO AWA ODO IWOYI KII PE DOJURU?
Ibeere Eketa;-SE ESE NI KI OBINRIN NI OKIKI TABI NI BURUJI DIE LOWO KI O TO LO ILE OKO NI?
Ibeere Ekerin;-NJE AWON OBI WA LEBI LORI ORO ILE YI? TI O BA RI BE KI NI EBI WON?
Ibeere Ikarun;-NJE AWON OKUNRIN LEBI LORI ORO ILE YI, TI O BA RI BE, KI NI EBI WON??
Ibeere Ikefa;-NJE ORO ILE YI NI ATUNSE BI? TI ATUNSE BA WA, KI NI ATUNSE OWUN GAN?
Ni Akotan;- KI NI AMORAN YIN FUN AWON OBINRIN, TI WON RI JAJE DIE, TI WON LOKIKI TABI TI WON NISE GIDI LOWO TI WON KO SI TI LO ILE OKO TABI AWON EYI TI O WA NILE OKO BAYI, ATI AWON TI O JE WIPE KI WON BI OMO KAN TABI MEJI KI WON SI DI IYA NDANGBE NI ILEPA WON???
Oro ree o, e jowo e ba wa dasi…..

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

History 101: What it takes to be a MENTALLY ENSLAVED FOOL in Your ancestral Land.

History 101: What it takes to be a MENTALLY ENSLAVED Harlequin in Your ancestral Land.

The quote for today is a page from Toyin Falola’s book, ‘Yoruba Warlords of the 19th Century’. To a lot of Yoruba Muslims. Islam means servitude to Usman Dan Fodio’s estate at Sokoto. They indulge in the same idiocy that led to the fall of the great Hausa civilization. Many Yoruba Muslims from Oyo are a dangerously brainwashed set of people that would pose future danger for the preservation of Yorubaland like their ancestors who pledged allegiance to Ilorin and ...