Home / Art / ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ OLÓÒGBÉ OLÓYÈ OLÁDÈJO ÒKÉDÌJÍ.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ OLÓÒGBÉ OLÓYÈ OLÁDÈJO ÒKÉDÌJÍ.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ OLÓÒGBÉ OLÓYÈ OLÁDÈJO ÒKÉDÌJÍ.

Ìdílé onígbàgbó ni Olóyè Oládèjo Òkédìjí ti wá. A bí i ní ìlú òyó, tíí se ìlú bàbá rè ní ojó kerìndínlógbòn, Osù kewàá odún 1929. Òun ló sìkejì omo méta tí ìyá àti bàbá rè bí. Ìlú òyó ni Oládèjo Òkédìjí ti lo ìgbà èwe rè. Nígbà tí ó di omo odún méfà ni ó bèrè ilé-ìwé. Ó lo sí ilé-ìwé ìjo elétò ti Àpáàrà, òyó, láàrin odún 1935 sí 1941. Ó tún lo odún méjì ní ilé-ìwé Ándérù mímó ní ìlú òyó Kan náà. Léyìn ìwé méfà, ó se isé olùkó ní Fìdítì, létí òyó, kí ó tó lo lo odún mérin ní Wesley college, ìbàdàn (1945-1948), láti kó isé olùkó onípò kejì. Òkédìjí kò dúro se isé olùkó ní agbègbè òyó mó léyìn tó ti parí èkó rè ní odún 1948. Díè nínú àwon ìlú tó ti se isé olùkó ni; Ìjèbú-òde, òwò, Èkó, Àkúré, àti Ilé-ifè. Ní sáà ètò èkó odún 1975/1976, Yunifásítì Ilé-ifè gba Oládèjo Òkédìjí láti kó èkó odún kan fún ìwé-èrí olùkó onípò-kínní. Oládèjo Òkédìjí se ìgbéyàwó ní odún 1953; omo Ìdó-Àní létí Òwò ni ìyàwó rè, Christiana Omolara. Omo márùn-ún; obìnrin mérin àti okùnrin kan ni Olórun fi ta wón lóre.

DÍÈ LÁRA ÀWON ÌWÉ TÍ OLÁDÈJO ÒKÉDÌJÍ KO.

  1. Àjàlólerù (1969).
  2. Àgbàlagbà Akàn (1971).
  3. Atótó Arére (1981).
  4. Ògá Ni Bùkólá (1972).
  5. Réré Rún (1973).
  6. Ìmúra Ìdánwò Yorùbá (1979).
  7. Sàngó (——).

“Bí Onírèsé ò bá fíngbá mó, èyí tó ti fín sílè ò lè parun.”

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

x

Check Also

Òsèré obìnrin tí ó tún jé Arewà, tí gbogbo ayé mò sí Adunni Ade se àfihàn ewà ara ré nínú sòkòtò pénpé.

Òsèré obìnrin tí ó tún jé Arewà, tí gbogbo ayé mò sí Adunni Ade se àfihàn ewà ara ré nínú sòkòtò pénpé. Gbajúgbajà òsèré orí ìtàgé se àfihàn ewà rè nínú àwòrán tuntun tí ó sèsè yà, tí ó sì dàbí egbin nínú aso ìwòsún tí a mò sí pyjamas tí ó wò sókè àti sòkòtò pénpé tí ó wò sí ìsàlè, tí ó sì gbé ewà rè hàn. Ó ya àwòrán náà ní àrà òtò, tí ó sì fi ...