Home / Art / Àṣà Oòduà / Ṣèyí Mákindé, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìpàdé ètò ọrọ̀ aje Nàìjíríà l’òun ti kó àrùn COVID-19
seyi makinde

Ṣèyí Mákindé, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìpàdé ètò ọrọ̀ aje Nàìjíríà l’òun ti kó àrùn COVID-19

Bí babaláwo bá ń kígbe ẹ̀fọ́rí, bóyá ni ìrètí aláìsàn kò pin o.

Bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé, ní ọjọ́ Ajé ti kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ pé òun náà ti dara pọ̀ mọ́ iye àwọn tó ti kó àrùn Coronavirus lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nǹkan bíi agogo márùn ún àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé ni Gómìnà Mákindé tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò rẹ̀ nínú èyí tó ti mọ̀ pé òun ti kó àrùn náà.

N tó ń se ọpọ èèyàn ní kàyééfì ní pé, níbo ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kó àrùn Coronavirus.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ fún Gómìnà Mákindé, Taiwo Adisa fi síta ṣàlàyé pé níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ ọrọ̀ ajé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NEC ni Mákindé ti fẹ́ẹ̀ kó àrùn ọ̀hún.

Gómìnà Mákindé wà lára àwọn Gómìnà tó farahàn níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde ọ̀hún ṣe sọ.

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé ọ̀hún ni ìgbìmọ̀ àwọn Gómìnà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà gba gbogbo àwọn Gómìnà tó wà níbi ìpàdé náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n lọ ṣe àyẹ̀wò ara wọn nítorí Ìròyìn tó ń jáde pé lára àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ti kó àrùn ọ̀hún.

Ìròyìn àyẹ̀wò Gómìnà Mákindé yìí ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n dá ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n kéde pé ó lárùn náà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sílẹ̀.

Alábọ̀dé Amẹ́ríkà kan ní ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n kéde pé ó ní àrùn náà nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, wọ́n sì ti dáa sílẹ̀ pé kí ó máa lọ sílé báyìí lẹ́yìn ìtọ́jú tó péye ní iléèwòsàn tí àyẹ̀wò míràn sì ti fihàn pé àrùn náà ti kúrò ní àgọ́ ara rẹ̀.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Auxiliary, ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú — Ìjọba Ọ̀yọ́ dúnkookò

Auxiliary, ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú — Ìjọba Ọ̀yọ́ dúnkookò Ó dà bí ẹni pé orí tí yóó súpó, kìí jẹ́ kí ti ọlọ́kùnrùn ó yè ni ọ̀rọ̀ fẹ́ dà báyìí fún asáájú ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àkóso gárèjì ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alhaji Mukaila Lamidi, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Auxiliary.Bí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe ń pa á lówe fún un pé ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú, àti pé pọnlá pọnlá a bàtá rẹ̀ yìí lè ya lójijì. Nígbà ...