Home / Art / Àṣà Oòduà / “Àṣejù Baba Àṣetẹ́” – Ìtàn bi Ojúkòkòrò àti Ìgbéraga ti jẹ́ Àṣejù
Cocoa farmer

“Àṣejù Baba Àṣetẹ́” – Ìtàn bi Ojúkòkòrò àti Ìgbéraga ti jẹ́ Àṣejù

Ni ìgbà àtijọ́, ọkùnrin kan wa ti orúkọ rẹ njẹ́ Ìgbéraga. Wọ́n bi Ìgbéraga si ilé olórogún, àwọn ìyàwó bàbá́ rẹ yoku ni ó tọ nitori ìyá rẹ kú nigbati ó wà ni kékeré. Lẹhin ti o tiraka lati pari iwé mẹ́fà, gẹ́gẹ́ bi ọ̀dọ́, ó gbéra lọ si ilú Èkó nibiti ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Ẹlẹ́ja.

Ó nṣe dáradára ni ibi iṣẹ́ ki ó tó gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ. Ìgbéraga pinu lati padà si ilú rẹ lati gba ogún ti ó tọ́ si lára oko kòkó rẹpẹtẹ ti bàbá rẹ fi silẹ̀. Ohun fúnra rẹ ra oko kún oko bàbá rẹ ti wọn pín fun. Ó di ẹni ti ó ri ṣe ju àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ ki gbogbo àwọn ọbàkan rẹ gbójú le fún ìrànlọ́wọ́.

 

Ni igbà ti ó yá, o ni ilé àti ọlà ju gbogbo àwọn yoku ni abúlé ṣùgbọ́n kò to, ó bẹ̀rẹ̀ si ra oko si titi dé oko àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ́ ki ó sọ àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku di alágbàṣe ni oko ti wọn jogún. Inú àwọn ọmọ bàbá rẹ wọnyi kò dùn si wi pé wọn ti di atọrọjẹ àti alágbàṣe fún àbúrò wọn ninú ilé ara wọn.

 

Yorùbá ni “Àṣejù Baba Àṣetẹ́”. Ìgbéraga bẹ̀rẹ̀ si ṣe àṣejù, kò dúró lati má a fi ọrọ̀ rẹ yangà si gbogbo ará ilú pàtàki si àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, ó jọ ara rẹ lójú, ó si nsọ ọ̀rọ̀ lai ronú tàbi gba ikilọ̀ àwọn àgbà ti wọn mọ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ. Kò mọ̀ wi pé ohun ngbẹ́ ikòtò ìṣubú fún ara rẹ́. Ni ọjọ́ kan, ó pe ọ̀kan ninú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ó sọ di alágbàṣe ninú oko rẹ tẹ́lẹ̀ ó si bu, ó pe e ni aláìní dé ojú rẹ. Ẹ̀gbọ́n ké pẹ̀lú omijé lójú pé “Bi ó bá jẹ ìwọ ni Ọlọrun, ma ṣe iwà burúkú yi lọ, ṣùgbọ́n bi ó bá jẹ́ enia bi ti òhun, wà á ká ohun ti o gbin yi”.

 

Alágbàṣe ni oko Kòkó ti wọn jogún – Working as Labourers in their inheritted Cocoa farm. Ni àárọ̀ ọjọ́ kan, Ìgbéraga ji ṣùgbọ́n kò lè di de nitori ó ti yarọ. Wọ́n gbe kiri titi fún itọ́jú ṣùgbọ́n asán ló já si. Ìṣòro yi jẹ ki ó ta gbogbo ohun ini rẹ ti ó fi nyangàn titi o fi di atọrọjẹ.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe àṣejù ohunkóhun kò dára pàtàki ki enia gbójúlé ọrọ̀ ilé ayé bi ẹni pé àwọn ti ó kù kò mọ̀ ọ́ ṣe, nitori Yorùbá sọ wi pé “kìtà kìtà kò mọ́là, Ká ṣiṣẹ́ bi ẹrú kò da nkan, Ọlọrun ló ngbé ni ga”.

 

 

English Version:

Continue reading after the page break.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete