Home / Art / Àṣà Yorùbá / A kú àmójúbà *Osù Ebibi (May) tuntun.
mayday

A kú àmójúbà *Osù Ebibi (May) tuntun.

A kú àmójúbà *Osù Ebibi (May) tuntun.* Osù ìségun àséwolè ni yóò jé. A kò níí se gégé ibi, béè ni ìkònà burúkú kò níí kò wá. Nínú Osù yìí, a ó ségun òtá ilé àti tòde, a ó réyìn àwon Afojúféni-mó-fokànféni. Òtá tó bá ní òun yó tìwá, ibi rere ni yóò já sí fun wa.

Òyè ní n là á bò lókè
Omo aráyé se bí ojúmó ní n mó
A dífá fún Agogo sékété
Tí n lo rè é pàdé òpá ní pópó
Òpá ni yóò ku
Agogo a sì gbélè
Iró ni wón ñ pa
Òpá ko le è pa Agogo
Abínú eni kò le è pa kádàrá dà

Àwon òtá kò níí rí ññkan burúkú gbé wa se o, béè ni won kò níí pa kádàrá wa dà sí láburú.

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

x

Check Also

Àbámẹ́ta

Ní Ojúmọ́ Ọjọ́ Àbámẹ́ta Tòní – #Kojoda #Yoruba #Orisa

Òsùn gbó ríró, kí o má dubúlẹ̀Òòró gangan laa bósùnÒsùn dé o Alàwòrò Ọlọ́run ọba ma jẹ kí gbogbo wa saarẹ Mo sé ní ìwúre fun orí kọ̀ọ̀kan wa ní ojúmọ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta tòní wípé àìsàn kéré tóbi aráyé kò ní fí se wá tọmọ tọmọ tebí taráỌlọ́run kò ní jẹ́ ka dùbúlẹ̀ àìsàn tọmọ tọmọ Gbogbo àìsàn arawa Olódùmarè yoo wòwá sàn kí ọ̀sẹ̀ yí tó parí