Home / Art / Àṣà Oòduà / Ààrẹ Buhari ní ààbò wà fún ẹ̀mí ààrẹ́ àná, Goodluck Jonathan
gej

Ààrẹ Buhari ní ààbò wà fún ẹ̀mí ààrẹ́ àná, Goodluck Jonathan

Ààrẹ Buhari ní ààbò wà fún ẹ̀mí ààrẹ́ àná, Goodluck Jonathan

Ààrẹ Buhari ti pe Ààrẹ àná, Goodluck Jonathan lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀,láti báa kẹ́dùn lórí ìkọlù àwọn agbébọn tó wáyé ní Òtuòkè tíí ṣe ìlú abínibí rẹ̀ nípìńlẹ̀ Bayelsa.

Nínú ọ̀rọ̀ orí fóònù náà, Ààrẹ Buhari kò fi bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ba òun nínú jẹ́ pamọ́. Ó ṣàkàwé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ ńlá tí ó sì kù díẹ̀ káátò.

Ààrẹ tún kan sárá sáwọn ṣọ́jà tó ń ṣọ́ Ilé Ààrẹ Jonathan fún bí wọ́n ṣe kojú ìjà náà gẹ́gẹ́ bí akin. Ó wá bá àwọn ẹbí ọmọ ogun tó ṣubú lójú ìjà náà dárò.

Ààrẹ Buhari wá fi dá àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà lójú pé àbò tó yẹ ń bẹ fún ẹ̀mí Ààrẹ àná náà àti gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà láì yọ ẹni kan sílẹ̀ àti pé ààbò ni yóó túbọ̀ máa jẹ ìṣèjọba òun lógún.

Ni Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìròyìn jáde síta pé àwọn agbébọn kan kọlu ilu Otuoke tó jẹ́ ìlú Ààrẹ àná, Ọ Omọ̀wé Goodluck Jonathan tí wọ́n sì pa ṣọ́jà kan níbẹ̀.

Fẹ́mi Akínṣọlá

#iroyinowuro

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Sofia Kenin

Sofia Kenin gba ife è̩ye̩ ìdíje Australia open 2030

Omo orileede American, Sofia Kenin, ti fi ebun re han si gbogbo agbaye pelu bi o se bori ifigagbaga asekagba laarin oun ati omo orileede Spain