Home / Art / Àṣà Oòduà / Àsírí Òkété
Àsírí Òkété

Àsírí Òkété

ÒKÉTÉ.
___
Òkété jẹ́ ọ̀kan nínú ẹranko abàmì tó lágbára púpọ̀. A sì máa gbé nínú ihò. ELÉDÙMARÈ fún-un ní àṣẹ púpọ̀.
Òkété kìí fi ọwọ́ tàbí ẹṣẹ̀ gbẹ́ ihò, ÌRÙ ni òkété maá n fií gbẹ́ ihò, fún ìdí èyí, ẹ ò le rí èrùpẹ̀ lẹ́nu isà òkété, bí ènìyàn bá gbẹ́ ihò òkété, ìgbà mìíràn a máa sé isà mọ́ èèyàn lọ́wọ́.

Tí abá gbẹ́ isà kan, òkété tí ó bá fi ahọ́n rẹ̀ Kan ilẹ̀, kò sí olúwarẹ̀ tí ó le ríi fà jáde.
Òkété tún ní àṣẹ kan ní ìparí Ìrù rẹ̀, bí ènìyàn bá n lé òkété lọ, tí ó bá fi àṣẹ Ìrù rẹ̀ na ilẹ̀, kò sí bí ẹni náà tile lágbára tó, yó subú lulẹ̀, àwọn ìdí èyí ló bí òwe Yorùbá tó sọ wípé
”Ọ̀RỌ̀ T’ÓKÈÉTÉ BÁ BÁ ILẸ̀ SỌ NI ILẸ̀ Ẹ̀ GBỌ”.

Tí ènìyàn bá pa òkété tí ẹni náà bá gé àṣẹ ìrù rẹ̀ sínú isà òkété náà, òkété náà yóò tún da padà wọ inú isà náà lẹ́yìn ọdún kan, èyí ló sì tún bí òwe Yorùbá tó sọ pé
”MI O LÈ FI ILẸ̀ BABA MI SÍLẸ̀, LÓ N S’EKÚ P’ÒKÉTÉ L’Ọ́DỌỌDÚN”.

Tí Òkété bá ti b’ímọ yóò yọ yàrá fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú Isà kan náà, wọn yóò yọ pálọ̀ síbẹ̀ èyí ni à n pè ní AGBURU ÒKÉTÉ, ibẹ̀ ni gbogbo wọn tí máa n jẹun.
Tí òkété bá ti darúgbó dáadáa tí ẹnu rẹ kò ran oúnjẹ mọ, àwọn ọmọ rẹ tí ó jẹ́ abo ni wọ́n ó ma fún-un lọ́yàn mu, èyí ló tún bí òwe Yorùbá tí ó sọ wípé
”BÍ ÒKÉTÉ BÁ DÀGBÀ, ỌMÚ ỌMỌ RẸ̀ NÍÍ MU”.

Òkété fẹ́ràn ÈKÙRỌ́ púpọ̀, ẹ̀kùrọ́ tí a bá rí nínú isà òkété, a kìí pèé ní èkùrọ́ ÈSÉ ni a má n pèé. Èyí ló bí òwe àwọn Yorùbá tó sọ wípé:
”KAKA KI OKETE MAJE EESE A FI SAWADANU NI”.

Òkété a máa dìde rìn bí ènìyàn lọ́gànjọ́ òru, yóó sì kó oúnjẹ lọ́wọ́ tàbí kí ó gbe oúnjẹ rù s’órí, ọdẹ tàbí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pa irú òkété tóbá wà ní ipò náà.

Orúkọ mìíràn fún òkété ni EWÚ, òkété Kìí jáde ní ọ̀sán. Èyí ló bí òwe ”A KÌÍ RÍ EWÚ LỌ́SÀN-ÁN”.
Tí ènìyàn bá gbẹ́ Isà kan òkété tàbí tó bá gbé àwọ̀n lélẹ̀, a ò gbọdọ̀ fa ìrù òkété yìí Jù kí ìrù rẹ̀ má baà bó, tí òkété bá b’órù mọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àmúbọ́ ló n fà.

Tí ènìyàn bá pa òkété tó n sùn lọ́wọ́ tó sì bu eérú sí ojú ọ̀nà rẹ̀, yóò rí ojú ẹṣẹ̀ òkété tó ti jáde padà, èyí ló mu àwọn àgbà máa pèé ní ÀKÚDÀÁYÀ….

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Seyi Makinde

Ṣeyi Makinde, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Sọ̀rọ̀ Lórí Àrùn Coronavirus Tó Ní

Ìròyìn tó bá ọ̀pọ̀ lẹ́jafùú ni ìròyìn ‘Mo ti ní àrùn Coronavirus’ èyí tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé gbé jáde ní ọjọ́ Ajé lójú òpó twitter rẹ̀. Níbáyìí tí ó ti lo ọjọ́ méjì ní ìgbélé lẹ́yìn ìkéde yìí, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé ti ṣàlàyé pé pẹ̀lú àánú Ọlọ́run, kò sí nǹkan tí Coronavirus leè fi òun àtàwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó ní àrùn náà ṣe. Mákindé tó ní òun dúpẹ́ fún òbítíbitì òjò àdúrà tí gbogbo èèyàn ń fi ...