Home / Art / Àṣà Oòduà / Edi Alálà !!!
ifa

Edi Alálà !!!

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? aku ijosin ifa toni to je ojo abameta, Olodumare ninu aanu re koni da emin wa legbodo lati le se pupo ijosin naa loke erupe o Ase.
Idanileko ti aaro yi jade lati inu odu mimo EDI ALÁLÀ, ifa yi gba awa omo eniyan niyanju wipe ki a mase ro ara wa pin, ifa ni opolopo lo ti ro ara re pin to siti so ireti nu wipe oun ko le se rere tabi lo lati ibikan sibi ikeji tabi dawole nkan ko si yori si rere, ifa sope kosi ohun ti Eledumare ko le se o, ifa wa fi afefe(efufulele) se akajuwe laarin awon nkan ti Olodumare seda wipe bi ako se nri afefe yi sugbon a ngba sara ko de sibiti ogo afefe ko buyo de lagbaye, bee gege naa ni igbesi aye omo eniyan naa seri o.
E jeki a gbo nkan ti ifa naa so.
Ifa naa ki bayi wipe:
Edi funfun ko níran
Atagoala ko mosù
Omo elésémopé
A difa fun èfùfùlèlè eyiti yio fe ka gbogbo aye won ni ki o karaale ebo ni ki o wa se nitori ki o ma baa rogun idena, obi meji, igba ewe ayajo ifa, èfùfùlèlè kabomora o rubo won si se sise ifa fun, bi èfùfùlèlè se bere sini nfe kaakiri gbogbo agbaye niyen to je wipe ko sibiti ki nfe de, gbogbo ibi ni okiki èfùfùlèlè kan de, o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin Olodumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi fun ori kookan wa wipe gbogbo ibi rere ti a ti ro wipe ako ni le debe ninu aye Olodumare yio sobe di aresepa funwa, okiki wa yio kan kaakiri agbaye si rere, afefe koni fe ko ma kan igi oko lara bi ara yin ba gba afefe ojo oni sara iwure ti mo se yi yio wasi imuse ninu igbesi aye yin oo Aaaase.
ABORU ABOYE OOO.

 

Faniyi David Osagbami

 

English Version

Continue reading after the page break

About ayangalu

One comment

  1. BalogunAdesina

    Ase

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...