Home / Art / Àṣà Oòduà / Eeto Owe L’esin Oro – 3

Eeto Owe L’esin Oro – 3

A ku deede asiko yii o ni aafin ilumoye, moki gbogbo wa kaabo si akotun eeto yin, eeto wa OWE L’ESIN ORO, oro l’esin owe ti oro ba sonu owe ni a o fi waa jade.
Ope nla lo si odo Oba Eledumare ti o je ki a tun ni anfaani lati tun pade leyin igba ti a dagbere ni ose to koja, enu ope wa koni kan oo. Moki kabiyesi olumoye akoko, awon olori, gbogbo ijoye patapata, awon igbimo aafin, omo’oba l’okunrin ati l’obinrin ati gbogbo olugbe aafin patapata ni moki n o ni olodi kankan oo.
Awon baba wa a ni ‘adebi eeyin maa sii, agbalagba ole nii’, ni bayii, e je ki a kanlu agbami eeto.
Lori eeto yi ni a o ti maa yannana awon owe ile wa lolokanojokan bi Olorun ba se gbawa ni aaye mon, ti a o si maa se alaaye itumo ati lilo awon owe naa.

Owe akoko ti a o gbeyewo lo bayii: OJO OWURO TI N BI OLOWO NINU, OLOWO GELETE, IWOFA NAA GELETE.
ITUMO; Fun apeere, olowo le je agbe to ni owo lowo, paapajulo ni aye atijo, ti o ni owo debi gee, ti awon eyan maa n wa ya owo lowo re, ti eyan ba si ya owo beyen ni aye atijo, o nilo oniduro, oniduro yii ni eni ti oju owo n pon yii yio fi duro, eyi to tumo si wipe yio maa ba olowo yii roko, yena ati lati maa se awon gbogbo ise agbara. Eyi ko ni din owo yii ku ti eni to yaa owo ba fe san pada o, oniduro yii ni won n pe ni IWOFA, o di ijo ti awon ebi re ba to ri owo san ki iwofa to le gba ominira lodo olowo re, ti eni to ya owo ko ba si ri owo san, iwofa di ajemogun niyen oo. Olorun koni fi oju owo pon wa ooo.
Tooo! Ise ti iwofa wa se ni ise oko, ti ojo ba wa suu tabi ti ojo ba nro arooda, bawo lo se maa ri, iwofa ko ni le lo roko, inu olowo o si nii dun…..agaga ti o ba lo je ojo owuro kutukutu, olowo a wa waa gelete lori ibusun, iwofa naa a waa gelete tabi ko jokoo, ko ni le sise.
ITUMO IJINLE; ti ohun kan ba sele to n di awon to n sise ooya won lowo, inu awon oga won o le dun, asiko yii l’owe yii maa n waye.

Owe keji fun toni lo bayii: ENI A GBOJU OKUN LE, KO JO ENI AAGBA.
Okun aagba je okun to le daada to see di igi tabi eru lati oko wa si ile. Ti a ba wa ro pe enikan lo le ran wa lowo, tabi pe enikan lo le se ohun kan, ti a ti gba eri iru eni bee je, to waa ja wa kule, iru asiko yii ni owe yii maa n foju ba ita wipe, “eni a gboju okun le, ko jo eni aagba”. Ti a ba ti n foju kan wo enikan tabi ti a ti gbe gege si ipele kan ti eni yii waa ja wa ni tanmo-on, asiko yii la maa n pa owe yii, eyi ni wipe ipele tabi ibi ti a fi eni yii si, a o ba a nibe.

Owe keta fun toni lo bayii: TI AGBALAGBA BA N BA OMODE JE IYAN EEWU L’OKO, GANMU GANMU IMU ENI NI N WOO.
iyan eewu ni iyan ojo keji, iyan yii maa ti wu, won maa wa re eewu ori re yii kuro ki o le ba see je, ko fii be toba fun agbalagba lati je iru iyan bayii, awon omode ni won maa n gbe fun. Ti agbalagba ba wa jokoo pelu omode ti won wa jo n je iru iyan yii, irun imu ati enu agbalagba yii ni omode naa yio maa wo, nitori o ti di dandan ki irun yii duro sarasara. oun gan koni fii be kobi ara si ounje naa nitori ounje naa ko yanju daada.
A maa n lo owe yii ti eyan ba n ba omode se apaara tabi eefe, ti omode naa wa ti fe so di arifin mowa lowo, ti ko fe bowo agba funwa mon. A le pa owe yii wipe, ti agbalagba ba n ba omode je iyan eewu l’oko, ganmuganmu imu eni ni nwoo.

Tooo, ni hainn ni a o ti se ewe le fun ti toni, agbala imo ati ogbon ni aafin ilumoye nibii ti a ti n ko arawa l’eko ti a si n ya ara wa l’ogbon. Aaye wa fun afikun, ayokuro tabi imoran lori eeto OWE L’ESIN ORO yii. Eyin eyan wa, e dasi eeto naa nipa wipe ki e funwa ni awon owe ti o tun ni ibamu pelu awon owe ti a na si afefe yii, ki atokun fi mon wipe, e gbo agboye awon owe naa, a o maa reti yin ooo. E seun

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete