Home / Art / Àṣà Oòduà / Ẹgbẹ ́Afẹ́nifẹ́re kọminú lórí ìwádìí ikú ọmọ Baba Faṣọranti to jẹ olori Afẹ́nifẹ́re – Odumakin
iroyinowuro

Ẹgbẹ ́Afẹ́nifẹ́re kọminú lórí ìwádìí ikú ọmọ Baba Faṣọranti to jẹ olori Afẹ́nifẹ́re – Odumakin

Ẹgbẹ ́Afẹ́nifẹ́re kọminú lórí ìwádìí ikú ọmọ Baba Faṣọranti to jẹ olori Afẹ́nifẹ́re – Odumakin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí eyín bá n pẹkẹ pẹkẹ,erìgì ni kò fálẹ̀ mójúṣe rẹ̀.
Ẹgbe Afenifẹre ti fi ero wọn han lori aijafafa ajọ awọn ọlọpaa lori ẹni to pa Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni ọjọ Isinmi Osẹ yii lọrọ naa ti jẹyọ.
Wọn ni Ọlọpaa ti n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa bi wọn ko si ti ri ẹni to pa arabinrin naa titi di asiko yii.
Odumakin sọ pe o ti le ni osu meji bayii ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti ko si aridaju pe ajọ Ọlọpaa ti ri ẹnikẹni mu lori ọran naa.

Bi a o ba gbagbe, arabinrin Olufunkẹ Ọlakunrin ti o jẹ ọmọ aṣiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, Rauben Faṣọnranti, ni awọn agbebọn pa ni popona Ọre si ilu Eko.
Ẹni ti o jẹ aburo si oloogbe naa, Kẹhinde Faṣọnranti ti sọ tẹlẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye pe awọn ọlọpaa ni darandaran lo ṣeku pa arabinrin naa.
Ẹgbe naa ni ọkan ninu awọn ẹri pe Ọlọpaa ko ṣakitiyan ni pe, wọn tete yọnda ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn pa arabinrin naa si fun ẹbi i rẹ.
Gẹgẹ bi wọn ti wi, wọn ni Ọlọpaa ko ṣe iwadii kankan lọwọ awakọ to wa arabinrin naa titi di asiko yii.

Siwaju si i, abajade ayẹwo lori bi iku naa ṣe jẹ ko i tii tẹ ẹbi naa lọwọ titi di asiko yii.
Ẹgbẹ naa wa n rọ gbogbo awọn ẹni tọrọ kan lati parọwa si ile – iṣẹ ọlọpaa ki wọn tete fi oju awọn ẹni ibi naa lede ni kiakia,ko le jẹ arikọgbọn fawọn oṣika wole ọla tó kù.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Samuel Ortom

Ilé-ẹjọ́ Tó Ga Jù Ní Samuel Ortom Náà Ló Tún Jáwé Olúborí Ní Benue

Ilé-ẹjọ́ tó ga jù ní Samuel Ortom náà ló tún jáwé olúborí ní BenueLáti ọwọ Yínká Àlàbí Iroyin yajoyajo to wole bayii lo n jeri sii bi ile ejo to ga ju lo to fi ikale si ilu Abuja se da ejo oludije fun ipo gomina ni ipinle Benue, iyen Emmanuel Jime ti egbe oselu APC nu bi omi isanwo. Awon adajo meje ti Adajo Olabode Rhodes-vivour je olori fun ni won se idajo naa ni nnkan bii ogbon iseju ...