Home / Art / Àṣà Oòduà / Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?
ibeji

Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò sí ìlú tí kò ní àdámọ́ ọ ti ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí nílùú Igbóọrà .Igbóọrà jẹ́ ìlú kan tó kalẹ̀ si agbègbè Ìbàràpá nipinlẹ Ọyọ, tí ìgbàgbọ́ sì wà pé kò sí ile kan nínú ìlú náà tí wọn kò ti bí ìbejì ìbẹta tàbí ìbẹrin níbẹ̀.

Kódà, àwọn ọmọ bíbí ìlú àti àwọn a àjèjì tó bá ń gbé nínú ìlú, tó ń jẹ oúnjẹ wọn, tó sì ń mu omi wọn, ni okun ìbejì àbi ìbẹta wà nínú rẹ̀.
Ọdọọdún sì ni wọ́n máa ń ṣe ọdún ìbejì nílùú náà, èyí tó tun kò lọdun yii.
Ọ̀kan lara àwọn ọba alaye ìlú Igbóọrà, Ọba Adedamọla
Badmus, tíí ṣe Olu-Aso ti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó sọ fáwọn oníròyìn pé, ìgbàgbọ́ wà pé ọbẹ̀ ìlasa àti àmàlà dúdú ló ń sokùnfà ìbí púpọ̀ nílùú ọhun.

Gẹ́gẹ́ bí ọba Badmus ti wí, o ti to aadọta ọdun sẹyin ti ilu Igbóọrà ti gbajúmọ̀ nípa bíbí ìbejì àbi ìbẹta, ohun tó sì tun jẹ́ pàtàkì ni pé, wọn kìí fi ìbejì tọrọ owó nílùú Igbóọrà. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé gbogbo ìdílé t’áwon ọmọ náà bá yà ni wọn má a ń kóríire ràn .

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Healthy Kidney

Akiyesi Pataki

Arákùnrin oníṣègùn oyinbo tó jẹ́ ọmọ bíbí Nigeria to wá n’ilu USA, fi ọrọ ìyànjú yí ranṣẹ fún anfaani ara wa. Jọ̀wọ́ ká, kí ó sì mú lo fún ìtọ́jú ara rẹ. Dr. A. Malgwi Ọna ti àwọn ọdọ wá lóde òní, ngba ni àìsàn kidirin jẹ ohun tó ndẹru báni. Mo nfi itẹjade yí ranṣẹ torí kò le ràn wá lọ́wọ́ nínú ewu àìsàn kidirin. Jọ̀wọ́ fara balẹ láti ka ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yí: AKIYESI PATAKI KIDIRIN WA GBA ÀMÓJÚTÓ ...