Home / Art / Àṣà Yorùbá / Ifa naa ki bayi wipe
opn ifa

Ifa naa ki bayi wipe

Aku ise ana o a si tun ku amojuba osu tuntun o, eledumare yio jeki osu yi tuwa lara o, ako ni bawon paruwo kosi kosi lase eledumare.
Laaro yi mo maa fi odu mimo ejioore se iwure fun yin gegebi ojo kinni ninu osu tuntun.
Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila ni moyò
Moni moyò
Orunmila ni kini mori ti mo nyo fun?
Moni ogoke otu ife ni, to fi iwaju gun ope to si feyin so kale pada laisi wahala
Oni se ko to òrò ayo ni?
Moni o toro ayo
Orunmila ni moyò
Moni moyò
Orunmila ni kini mori ti mo nyo fun?
Moni àgbè mùyoko otu ife ni, ti won lo soko lati ibere Odun ti won de lopin odun ti won si roko bodunde
Oni se ko to òrò ayo ni?
Moni o toro ayo
Orunmila ni moyò
Moni moyò
Orunmila ni kini mori ti mo nyo fun?
Moni awon aboyun otu ife ni, ti won ru oyun fun osu mesan gbako! Ti won si bi tibi tire laisi wahala
Oni se ko to òrò ayo ni?
Moni o toro ayo
Moni Orunmila kilode to fi nfo bi ede bi eyo?
Orunmila loun ko fo bi ede bi eyo
Oni bi kose ire ayo toun ri niwaju akapo toun
Oni omo kan tuntun ni eleyi ti won maa bi ki won so omo naa ni MOYÒ.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure wipe osu tuntun yi yio je osu ayo, idunnu ati ilosiwaju funwa o, aye yio bawa yayo nkan rere o, osu yi yio san wa ju gbogbo osu to ti koja lo o aaaseee
ABORU ABOYE OOO.

English Version

Continue after the page break bellow.

 Diesel Generators for sale

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Ẹ̀rìndínlógún !

Ẹ̀rìndínlógún Èjì Ogbè Ogúnlénírinwó okọ́ Ọ̀tàlélégbèṛin àdá Wọ́n dárí jọ Wọ́n ń lọ bókè jagun Òkè kò jẹ Òkè kò mu Òkè ni yíò ṣẹ́tẹ̀ gbogbo ajogun. Twenty and four hundred hoes Sixty and eighty hundred machetes They conspired And launched a war against Oke, the Hill Oke does not eat Oke does not drink Oke will defeat the plot of all malevolent forces