Home / Art / Àṣà Yorùbá / Ìjọ Kátólíkì Bẹ̀rẹ̀ Ìwáàdì Lẹ̀yìn Tí Àwọn Sisitá Méjì Lóyún Ójijì
katoliki

Ìjọ Kátólíkì Bẹ̀rẹ̀ Ìwáàdì Lẹ̀yìn Tí Àwọn Sisitá Méjì Lóyún Ójijì

Ìjọ Kátólíkì bẹ̀rẹ̀ ìwáàdì lẹ̀yìn tí àwọn sisitá méjì lóyún ójijì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Eemọ̀ lukutu pẹ́bẹ́,kò síbi tí ìṣe ò sí. Ayé dojú kejì, wọ́n ń bámí ẹran níhòòdí ọmọ èèyàn. Ìjọ Kátólíìkì ti ń ṣe ìwádìí bí àwọn sista méjì kan ṣe lóyún lẹ́yìn tí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nílẹ̀ Áfírìkà. Àwọn obìnrin méjéèjì náà tó jẹ́ olùgbé ìlú Sicily, lórílẹ̀-èdè Italy, tí wọ́n kìí ṣe ọmọ ìjọ kan náà, ni wọ́n ń dúró de ọjọ́ ìkúnlẹ̀ báyìí.


Ọ̀kan lára àwọn obìnrin ọ̀hún, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ sí ilé ìwòsàn nítorí inú rírun, kí Dókítà tó fún- un ní ìròyìn pé oyún ti dúró sára rẹ̀.
Ìjọ Kátólíìkì tó wà ní ìlú Rome sọ fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé, ìgbà tí àwọn obìnrin náà rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ adúláwọ̀ ni wọ́n ní ìbálòpọ̀.
Ìjọ ọ̀hún tẹ̀síwájú pé àwọn obìnrin náà rú òfin tó jẹ mọ́ Ẹ̀sìn àti iṣẹ́ tí wọ́n gbà, bẹ́ẹ̀ ni ìwádì ti bẹ̀rẹ̀ lori bí wọ́n ṣe di aláboyún òjijì.


Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni olórí ìjọ Kátólíìkì lágbàáláayé , Pope Francis ti sọ ṣaájú pé, àwọn Bísọ́ọ̀bù kan má ń fi ipá bá àwọn sista ní àjọṣepọ̀, kódà ó ní wọ́n ń fi àwọn mìíràn lára wọn ṣe ẹrú ìbálòpọ̀. Popu ṣàlàyé pé, bí àwọn Bísọ́ọ̀bù yìí ṣe ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin náà jẹ́ ìsòro ńlá nínú Ìjọ Kátólíìkì.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Photos: Agògòrò Èyò in Sao Paulo Brazil

Oodua (Yoruba) culture and heritage is very rich.Eyo is to honour our Ancestors.I had to join the Eyo in a dance at the celebration of Egbe Omo Oduduwa in Brazil 30th November 2019 especially being a participant myself when late Oba of Lagos, Alayeluwa Oba Adeyinka Oyekan honored my late father with Eyo Awise Akano Fasina Agboola in 1975.From Araba of Oworonsoki land Lagos Nigeria