Home / Art / Àṣà Yorùbá / Ó DỌWỌ́ ORÍ

Ó DỌWỌ́ ORÍ

Ó DỌWỌ́ ORÍ

Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá dọwọ́ Orí ẹ̀ láyé;
Àlámọ̀rí ọmọ ẹ̀dá ènìyàn;
Ó kúkú ń bẹ lọ́wọ́ Oríi wọn gbogbo.
A díá fún PMB ẹni àyànmọ́.
A bù fún PYO ẹni Orí ṣe lóore.
Lọ́jọ́ tí wọn ó darí ilẹ̀ yìí pẹ́.
Àwọn kẹ́nimánìí fọnmú;
Wọ́n ní kò ní jẹ́ níṣojú àwọn.
Wọ́n ní ti PMB ti PYO;
Wọn ò ní pẹ́ nílé ọlá.
Wọ́n ṣakitiyan títí, wọ́n ṣaápọn.
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀;
Ibi wọ́n ní gbégbé ò ní gbé, ló gbé;
Ibi wọ́n ní tẹ̀tẹ̀ ò ní tẹ̀, ló tẹ̀ gbẹ̀yìn.
Ohun gbogbo dọwọ́ Orí ẹ̀dá.
Ọ̀rọ̀ gbogbo dọwọ́ àkúnlẹ̀yàn.
Àyànmọ́ ẹ̀dá ò ṣeé dọ́gbọ́n sí.
Bó ti wù káyé ó sáré tó;
Iwájú ni wọ́n á máa bálẹ̀ẹ́lẹ̀.
Àlámọ̀rí ẹ̀dá dọwọ́ Orí ẹ̀ láyé.
Ọ̀tá pète-pèrò;
Wọ́n fẹ́ rán PMB níwo ẹṣin lọ;
Ọpẹ́lọpẹ́ inú mímọ́.
Wọ́n rọ́bọn lu jíìbùu rẹ̀;
Bíi kó kú bíi kó kú.
Oríi baba ló kó baba yọ.
Àwọn amọbiṣebi tún bùṣe gàdà;
Wọ́n fún un ní májèlé;
Ọmọ Bùhárí tún ta á tu ni.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ló ṣe bí London ní ó ṣàìsí sí;
Baba Sáárá tún dé tán;
Ẹ tún ní kì í ṣòun gan-an ni.
Ẹ lọ́mọ orílẹ̀-èdè Sudan;
Tí í jẹ́ Jubril nọ́n gbé wálé.
Ẹ palá lẹ́nu títí, ẹ tún jẹ jowolo.
Ọkọ Aáìṣá ò dún pẹ́kẹ́;
Ibi baba Àlímọ́tù ń lọ, ló ń lọ.
Orúkọ tó wù wọ́n ni wọ́n pè é.
Ayé tún ń fẹ́ ti baba Yèsúùfù.
Ǹlẹ́ akin nínú ọmọ Dàùra.
A-dá-wọn-lẹ́kun-ìwà-ìbàjẹ́.
A-bá-wọn-jà-má-jẹ̀bi-wọn.
Ọkùnrin dùgbẹ̀dùgbẹ̀ bí igi àdárọ̀.
Olóòótọ́ nínú olóṣèlú ìwòyí;
Ẹni alátakò ń kọ́minú ẹ̀;
Tí ò kọminú baba-ńláa wọn.
Akọgun má kọ̀jà ẹni àyẹ́sí.
Ààrẹ pàtàkì;
Tí gbogbo dúníyàn ń gbé gẹ̀gẹ̀.
Ikútańtì ọkùnrin takuntakun.
Àwòròpàyí olóòótọ́;
Kúdińkàn nínú akíkanjú akọni.
Ó fi gbígbọ́ ṣaláì gbọ́;
Àwọn alásọgbọnnu ládití ni.
Ó fi rírí ṣaláì rí;
Àwọn ẹlẹ́numàrímàsọ láfọ́jú ni.
Ó fi mímọ̀ ṣaláì mọ̀;
Wọ́n tún ní ó ti ṣàfẹ́kù ọpọlọ.
Káre láé;
Ẹni àwọn ẹniire yàn láàyò.
Káàbò sí orí àpèrè Ààre wa.

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

x

Check Also

Olójòǹgbòdu: The Wife of Death.

Sculpture at the Àkòdì Òrìṣà, Ile Ife, Nigeria