Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Irosun Afin/ofun
opn ifa

Odu Ifa Irosun Afin/ofun

| | |
| |
| | | |
| | |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin tu ku isimi opin ose, eledumare yio rojo ibunkun sinu aye wa loni o ase.
Odu ifa IROSUN AFIN/OFUN lo gate laaro yi, ifa yi fore Omo aridunu fun akapo ti odu ifa yi ba jade si, ifa ni ki o bo orisa nla daradara nitori orisa yio fi Omo ologo rere ta lore laipe, ki o si ta afin to wa ni agbegbe re lore .
Ifa naa ki bayi wipe: Afin ko se ba sere ale, to ba di ale a maa sebi eniti o tobi a dabi eniyan pataki laaro a difa fun orisa nla oseremogbo lojo ti baba yio fi gbogbo Omo re bi funfun ninini won ni ki baba karale ebo ni ki o wa se nitori ki awon Omo naa le yan ki won tun le yanju ki won si le ni okiki rere kaakiri agbaye, obi meji, agbebo adiye funfun, igba iyan funfun, obe egunsin funfun, igbin ero, agba otin ati igba ewe ayajo ifa, orisa nla si kabomora o rubo won se sise ifa fun, ko pe ko jina baba wa bi opolopo Omo pelu awo funfun ninini, gbogbo won si yan won yanju won si lokiki kaakiri agbaye ijo ni orisa nla wa njo ayo ni orisa nla nyo o nyin awo awon awo re nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu Omo nje jebutu Omo ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio da gbogbo eniti nwoju re fun Omo bibi lohun laipe, gbogbo awon Omo wa yio se orire won yio yan won yio yanju won yio ni okiki rere kaakiri agbaye, ako ni bawon bimo papanlagi, orisa nla yio si ro ojo ibunkun re sinu igbesi aye wa lati oni lo ati titi ayeraye ni oruko Orunmila mimo(B.A) alagbawi wa aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

ENGLISH  VERSION: 

Good morning my people, how was your night? Hope it was greatly enjoyed, wishing you all a vibrant weekend, may God in his abundant mercy bless us today ase.
It is IROSUN OFUN/AFIN corpus that revealed this morning, ifa foresee the blessing of intelligent child for whoever this corpus revealed out for, ifa advised him/her to feed orisa nla very well so that orisa nla may quickly answered his/her prayer for giving him/her a decent child and he/she should give gift to albino that is living in eviron .
Hear what the corpus said: An albino is dangrous to be playing with at night, they used to act as a big person at night and feel like a distinguished person in the morning cast divined for orisa nla oseremogbo when he would give birth to all his child in white colour he was advised to offer sacrifice for his oke iponri so that his child may be famous and well prosper around the globe, two kola nuts, white hen, white pounded yam, white melon soup, snail, gin and ifa leaves and orisa nla complied, aftermath orisa nla gave birth to plenty child in a white colour and they all became successful and have a great fame in life, he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.

 
My people, I pray this morning that heavenly father will answered those that were/are looking for his eyes for child quickly, all our child will become distinguished and famous person, we shall never mourn over our child and the blessings of orisa nla will be flowing over us forever and ever by the mighty name of Orunmila (B.A) ase.

 

Cc- Faniyi David Osagbami

About ayangalu

One comment

  1. Eniola Otunba.

    Good morning sir. Thank a lot for the posts on this site specifically posts about odu ifa. Several times I visited this site to learn about some odu ifa. This morning I just learned about another one: Irosu Ofun. I’m initiated a few years ago but I don’t know much about odus. So your site is a teacher for some new initiates like me. I do cast ifa. I know how to cast but the message contains in the odu I don’t know. So please can you tell me about the following odu Ifa: Ofun Oyekou? It’s oriki, it’s taboos and what exactly that odu is saying. Thank you sir. Aboru aboye abosise.

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete