Home / Art / Àṣà Yorùbá / Odu ifa IROSUN OSE/ALAJE
ifa

Odu ifa IROSUN OSE/ALAJE

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isinmi ana o, Olorun eledumare yio jeki aje fi ile wa se ibugbe loni o ase.
Odu ifa IROSUN OSE/ALAJE lo gate laaro yi, ifa yi fore aje lopolopo fun akapo ti o ba jade si sugbon ki o bo orisa aje daadaa, ki won si se ise ifa re fun, ifa ni akapo yi koni bawon rahun owo nile aye re.
Ifa naa ki bayi wipe:
Irosun sékésèkè séké babalawo aje difa fun aje lojo ti o ntikole orun bo wa sikole isalaye won ni ki o Karale ebo ni ki o wa se nitori to ba dele aye ki o baa le di eni ajiki ki o ba le deni ajige, obi meji, eyele funfun, ekuru funfun, ogede omini, otin, oro oyin, igba ewe ayajo ifa, aje kabomora aje rubo won se sise ifa fun, aje wa dele aye o di olokiki o di eni nla o di eni ajiki o di eni ajige, nje bi omode baji ekun aje ni won a maa sun bi agbalagba baji ekun aje ni won a maa sun bii toto aje wa bere sini njo o nyo o nyi awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nba awo lese obarisa.

Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi bi a se njade lo olorun Eledumare yio fi owo ara meriri se iyanu laye wa, ao si gba ipe idunnu ti ako ro tele loni ti yio si so wa di olorire eniyan ki ato pada sile, aje yio maa bawa gbele ni gbogbo ojo aye wa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

ENGLISH VERSION:

Continue after the page break

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

Enter Captcha Here : *

Reload Image

x

Check Also

Gómìnà Obina náà dìbò níbi ìdìbò Anambra.

Gómìnà Anambra Willie Obiano náà dìbò fún ara rè ní Otuocha ward 1 unit 004.