Home / News From Nigeria / Breaking News / Odu ifa OKANRAN OSA
baba ifa

Odu ifa OKANRAN OSA

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Mo lero wipe gbogbo wa la sun dokan daradara aku isimi opin ose o.
Odu ifa OKANRAN OSA lo gate laaro yi, ifa yi gba eniti o ba jade si niyanju wipe ki o se etutu daradara ki won si se akose ifa yi fun ki o fi sin gbere sorun owo re mejeeji ki o si tun maa mu dani fun fifi se adura pelu, ifa ni nitori ki o ma baa maa se Ogun amubo ati aseti ki gbogbo nkan to ba ndawole baa le maa yori si re. Ifa yi gba okunrin ti odu yi ba jade si niyanju wipe ki o se etutu naa ki o ma baa maa se amubo iyawo , ki iyawo ba le ba gbele dojo ale, ti o ba si je obinrin naa lo jade si ki o se etutu naa daradara o ki o ma baa ni isoro Oko ki won ma baa maa gbe lagbeju sile ki o ba le lade lori dojo ale re.

Ifa naa ki bayi wipe: okan sa eji sa babalawo Asa difa asa lojo ti o nroko iwaje, beeni asa si nse Ogun amubo o nse Ogun aseti o wa goke ijeti ile Orunmila won ni ko karale ebo ni ki o se ki o ma baa maa se amubo ati aseti mo ki o baa le maa ri eran paje, obi meji, emu 3, eko 4, akara 4, igiripa obuko esu, egbaa meta o kabomora o rubo won ni ko gbe lo sorita meta ajaloko asa si se bee, nigbati o dorita meta o wa nse adura si etutu ni esu odara de, o wa beere lowo asa wipe kini isoro re? Asa ni Ogun amubo ati aseti lo nba oun finra pe kosi gbogbo nkan toun ba mu ti ki nbo lowo oun, esu ba mu ikan ninu emu ti asa fi rubo yen o fi ikan si lowo otun o fi ikan si lowo osi oni kosi nkan to bati mu ti yio bo lowo re mo inu asa ba dun to ba wati ri nkan to fe gbe asa a so wipe apasa maa ni o han so, o maa so wipe Oko asa nko? Mani ki nbale nsawon, lati igba naa ni asa ti segun Ogun amubo ati aseti o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.

Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ire aye wa koni bo danu lowo wa mo, ao maa ni aseyori lori gbogbo adawole wa, gbogbo obinrin ti won nse amubo Oko yio di asegun loni e o si lade lori dojo ale yin, gbogbo okunrin ti won nse amubo iyawo won yio di alaya ni odede, ako ni sanwo ire gbogbo mo laelae, laalaa wa koni jasi asan lase eledumare aaaseee. ABORU ABOYE OOO.

 

English VERSION

It is OKANRAN OSA corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice so that he/she will not suffering from dropping down of goodnesses and unsuccessful in all his/her endeavors. If this kind of corpus revealed out for man, ifa advised him to offer sacrifice because of the problem of wife, so that he won’t experience the breakdown of relationship every time or not be able to seek for partner and also vice versa for woman and the akose must be done for him/her to mark it round his/her two wrists and there is one that will be using for prayers.

Hear what the corpus said: okan so eji sa the priest of eagle cast divined for eagle when eagle was going for hunting eagle was suffering from dropping down of goodnesses, eagle was advised to offer sacrifice so that no goodnesses will be dropping down from its hands anymore, two kola nuts, (three local pliers), corncake 4, cake beans 4, he-goat, three shillings and ifa leaves, eagle complied and was instructed to placed it in three junctions and eagle did so, when eagle was doing prayers esu odara emerged and he asked eagle that what problem is? Eagle responded that whatever things it lay hands on does not prosper and it’s suffering from dropping down of goodnesses, so esu odara took one out of that three local pliers and he put one of it on the eagle right hand and one on the left hand and he told eagle that nothing will be dropping down from its hands as from today, and truly since then whatever eagle catching will not dropping down from its hands eagle started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.

My people, I pray this morning that our goodnesses will never dropping down from our hands anymore, we shall be succeeded in all our endeavors, those women that were suffering from dropping down of husband will never experience that anymore and those men that were suffering from dropping down of wife will never experience that too, we shall never work in vain ase.

 

Ifaniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...