Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Owonrin Meji
Odu Ifa Owonrin Meji

Odu Ifa Owonrin Meji

| | | |
| | | |
  |   |
  |   |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana, eledumare yio pese fun aini wa loni ase.
Odu ifa OWONRIN MEJI lo gate laaro yi, ifa yi fore pupo fun akapo ti odu ifa yi ba jade si, ifa ni akapo yi yio ri ere pupo lori ise re tabi lori owo re ti akapo yi ba le rubo daradara, ifa ni ise meji ni ipin akapo yi yan wa lati ode orun, ti o ba je okunrin ni a difa yi fun ao sofun wipe ki o lo maa sise àgbè/ogbin, ti o ba de je wipe obinrin ni a difa yi fun ao sofun wipe ki o maa se ise òwò/ oja tita, ifa ni ise mejeeji yi lo ba aisiki awon mejeeji mu.
Ifa naa ki bayi wipe:
Okesewu sigidi babalawo okewu difa fun okewu eyiti yio roko la waye, won ni ki o karale ebo ni ki o se ki o baa le ri ere pupo loko re bo wa sile (obi meji… igba ewe ayajo ifa), okewu kabomora o rubo won si se sise ifa fun, okewu wa de oko o wa gbin orisirisi nkan ere oko gbogbo ere oko naa lo si mu eso rere jade to si ta won lówó nla, okewu wa di olowo o di oloro o wa kere oko bo wa sile o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo ni gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire jebutu ire ni a nba awo lese obarisa.
Okewu wa fiyere ohun bonu wipe: nje kini okewu rola? Oko! Oko ni okewu rola oko.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo adawole wa yio yori si rere, ise wa yio mu ere lopo yanturu jade, ao kere oko dele, ako ni se lasan lase eledumare.
ABORU ABOYE OOO.

 

ENGLISH VERSION:

Good morning my people, how was your night? Hope it was great. I pray that God will be with us and provide for our lacks today ase.
It is OWONRIN MEJI corpus that revealed this morning, ifa foresee the blessings of great profit over work/business for whoever this corpus revealed out for, ifa advised him/her to offer sacrifice, also ifa made he/she understand that his/her destiny choose two works from the heaven while coming to the earth, if this person is a man he can venture into farming because he would achieve greatly from farm and if it is a woman, she can also do farming or business, the both jobs are compatible with their destiny.
Hear what the corpus said:
Okosewu sigidi the priest of okewu cast divined for okewu the one that will become rich from through farming, he was advised to offer sacrifice, (two kola…………………………and ifa leaves) and he complied, aftermath all the crops of okewu produced bountifully and he sold them with big money, okewu became greatly rich he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
He started singing the song of ifa that; what did okewu did to make money? Farm! it is farm that okewu was made money.
My people, I pray this morning that whatever will lay our hands upon shall be prosper, our works/businesses will be profitable and we shall never work in vain ase.

Cc – Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...