Home / News From Nigeria / Breaking News / Odu Irosun Onisin
Ogbe Rikusa ifa Divination

Odu Irosun Onisin

| | |
| |
| | |
| | |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isimi oni o a sin tu ku orire ose tuntun yi to tun soju emin wa, olorun eledumare ninu aanu re yio ro ojo ibunkun lopolopo sinu aye wa ninu ose yi ase.
Odu IROSUN ONISIN lo gate laaro yi, odu ifa yi fore isegun lori awon eleye fun eniti odu ifa yi ba jade si, ifa ni akapo yi njagun eleye gidigidi, ifa ni awon eleye ko jeki igbesi aye re ni ilosiwaju ifa ni sugbon yio segun won nipa ebo riru o.
Ifa naa ki bayi wipe: Osa ile o paja ilasa Omo olokun bi eniyan a difa fun Orunmila lojo ti baba nbe laarin ota Omo eleye, won ni ki Orunmila karale ebo ni ki o wa se ki o baa le segun awon ota Omo eleye, obi meji, eko 4, akara 4, apata okete, epo pupa, eyin adiye meta, iyo, igba ewe ayajo ifa, Orunmila kabomora o rubo won si se sise ifa fun ko pe ko jina ifa se fun Orunmila o segun awon ota Omo eleye o leke won baba wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo awon eni okunkun ti won ko bafe ki igbesi aye wa ni ilosiwaju yio di eni agbegbin lojiji, Ogun awon ota Omo eleye koni bori wa o gbogbo awon eleeru(ashes) eda nile baba re, nile iya re, nile oko/aya re tabi lagbegbe ibiti oun ngbe ti won duro soju ona ise rere re ti won nba ogo re je loru oganjo won yio di eni igekuro lori ile alaaye lojiji nipase ase ti a fun Orunmila mimo alagbawi wa aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English version

Good morning my people, happy sunday and I wish you a bountiful new week, may Olodumare in his abundant mercy shower a rain of blessings on us this week.
It is IROSUN ONISIN corpus that revealed this morning, ifa foresee the power of victory over witches for whoever this corpus revealed out for, ifa said this person has been battled with bad spirits for a long time but he(ifa) promise that he/she will conquer them if he/she can offer a prescribe sacrifice.
Hear what the corpus said: Osa ile o paja ilasa Omo olokun bi eniyan it cast divined for Orunmila when he was at the midst of witches his enemy, he was advised to offer sacrifice so that he could be victorious over them, two kola nuts, corncake 4, cake beans 4, big rat, local eggs 3, palm oil, salt and ifa leaves and Orunmila complied also the ifa medicine was made for him, aftermath Orunmila conquered the fight against witches, he quenched the power of darkness that is disturbing his progress he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.

 
My people, I pray this morning that any spirit of darkness disturbing our progress shall be suddenly buried, the war of witches will never over power us, all those rustic evil minded in your father’s house, mother’s house, and in your matrimonial home or environs standing against your success shall be cut off suddenly on the land of Olodumare by the authority given to Orunmila (B.A) Ase.

 

 

About ayangalu

One comment

  1. Ase.. Can you pls explain odu Ifa “OSA IRETE” aka “OSA OlOYON”

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...