Home / Art / Àṣà Oòduà / Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola

Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola

Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola ni wọn bí ní ọjọ́ kẹrìnlélọ́gún oṣù Ọ̀pẹ ọdún 1939 (24 December 1939) wọn jẹ́ òsèsé, ohun kọ̀wé, Oluṣiṣẹ nípa èdè Yorùbá. A mò wón sí kíkọ ìwé ni èdè Yorùbá, wón sì tún gbé èdè Yorùbá lárugẹ.
Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola ni wón bí ní ìlú Ìbàdàn, wón lọ sí ilé ìwé Labode Methodist àti Wesley College. Wọ́n lọ sí ilé ìwé gíga Fáṣítì Ìbàdàn níbi tí wọ́n tí kó nípa èdè Faransé (French), bàbá tún lọ sí Fáṣítì Ẹ̀kọ́ láti lọ kó nípa lítírésọ̀ èdè Yorùbá ni odun 1978 kí wón tó sise ní Fáṣítì Obafemi Awolowo ni ìlú ilé Ifẹ̀.
Wọ́n yan Akinwumi Ishola ni Ọ̀jọ̀gbón ni Fáṣítì Obafemi Awolowo ni ọdún 1991. Bàbá Akinwunmi Ishola kọ eré onise Efúnsetán Aníwúrà láàrin ọdún 1961 sì 1962 nígbà tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni Fáṣítì Ìbàdàn. Kò pèé ni wón kọ ìwé Ó lekú ní ọdún 1986.

Bàbá tún kọ orin ẹ̀rí ilé ìwé gíga tí wọ́n ń kọ ní ilé ìwé gíga Wesley Ìbàdàn lónìí.

Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola tún kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré onise àti ìwé. Bàbá tún sise olugbohunsafefe, wọn tún dá ilé isẹ ìgbé eré ìjáde leyi tí ó jé kí wọn ṣe àwọn ìwé tí wọ́n kọ sí eré tí wọ́n ń gbé jáde lórí móhùnmáwòrán. Bàbá kọ ìwé ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì tú sí èdè Yorùbá.

Ní ọdún 2000 bàbá gba àmìẹyẹ fún isẹ takuntakun wọn (National Merit Award) lẹ́yìn tí wọ́n tún lọ kàn sí Ọ̀jọ̀gbón Fáṣítì Georgia ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola fẹ́ ìyàwó tí wọ́n sì bí ọmọ mẹ́rin.
Ọ̀jọ̀gbón AKINWUMI ISHOLA kú ní ọjọ́ mẹ́tàdínlógún oṣù Ẹ̀rẹ̀lẹ́ ni odun 2018 sí ìlú Ìbàdàn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Kí èdùmàrè ó gba àbọ̀ bàbá, iwájú tí wọ́n dójú ko yìí ó dára, ẹ̀yìn tí wọ́n fi sílè kò ní bàjé.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete