Home / Art / Àṣà Oòduà / Omo ìbàdàn

Omo ìbàdàn

Omo ìbàdàn

Ìbàdàn mèsi ògò, n’ílé olúyòlé.
Ìlú ògúnmólá, olódò kèri l’ójú ogun.
Ìlú ìbíkúnlé alágbàlá jáyà-jáyà.
Ìlú Àjàyí , ò gbórí Efòn se fílafìla.
Ìlú Látóòsà, Ààre-ònà kakanfò.
Ìbàdàn Omo ajòro sùn.
Omo a je ìgbín yó, fi ìkarahun fó ri mu. ìbàdàn májàmájà bíi tojó kín-ín-ni,
èyí tó ja aládùúgbò gbogbo ológun
Ìbàdàn kìí bá ni s’òré àì mú ni lo s’ógun.
Ìbàdàn Kure!
Ìbàdàn bèèrè kí o tó wò ó, Nibi Olè gbé n jàre Olóhun.
B’íbàdàn tí ń gbonįlé béè ló n gbe Àjòjì.
Eléyelé l’omi tí t’erú-t’omo ‘Láyípo ń mu. Àsejíre l’omi abùmu-bùwè n’ílè ìbàdàn.

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

x

Check Also

Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Fẹ́mi Akínṣọlá Ṣe aifẹsọ kebosi,lai rẹni jo o,ati pe n ta o ba fẹ o bajẹ,o ni bi o ṣe yẹ ka ṣe e,eyi lo bi atunse abẹnu lati fopin sawuye wuye to waye latari aawọ to suyọ laarin awọn onisese ati awọn ẹlẹsin meji ti o ku(Kitẹẹni ati Musulumi).Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.Kareem, ẹni to soju ...