Home / Art / Àṣà Oòduà / Ambode ti yan oga agba tuntun fun ileewe LASU
Olanrewaju Fagbohun

Ambode ti yan oga agba tuntun fun ileewe LASU

Gomina Ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode ti yan Ojogbon Olanrewaju Fagbohun gege bi oga agba tuntun fun ileewe Ifafiti ti ipinle Eko, LASU. Ikede yii lo waye ninu atejade ti komisanna fun eto iroyin ati agbekale ilana, Ogbeni Steve Ayorinde fi sita.

Ojogbon Fagbohun ni yoo je enikejo ti yoo maa tuko ileewe giga naa lati igba ti won ti se idasile re lodun 1983.

Ojogbon Fagbohun to gba imojinle kofeso ninu imo ofin to niise pelu ayika eni ni won bi ni ojo kerindinlogun osu kewaa odun 1966. Iwe akosile itan aye re si fi ye wa wi pe, Akesan to wa ni ijoba ibile Alimoso niluu Eko ni Ojogbon naa ti wa.

Odun 1991 ni Ojogbon Fagbohun gba ise ni ileewe LASU gege bi amugbalegbe olukoni. Eyi lo se titi to fi de ipo agba gege bi igbakeji ojogbon lodun 2004.

Ojogbon Fagbohun ti fi igba kan je okan lara awon igbimo alase ileewe naa ri. Aimoye eka eko lo si ti se adari fun ki gomina to fi leta ayo ranse sii gege bi eni ti yoo je oga agba ati oludari Lagos State University to kale siluu Eko.
http://www.olayemioniroyin.com/

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb