Home / Art / Àṣà Oòduà / Sambo Dasuki wo gau! Falana setan lati gbe lo si ilejo idaran ti okeere
Dasuki Sambo

Sambo Dasuki wo gau! Falana setan lati gbe lo si ilejo idaran ti okeere

Agba ninu ise amofin to tun je agbejoro ti n ja fun eto omoniyan, Ogbeni Femi Falana ti seleri lati gbe oludamoran nipa eto abo fun ijoba apapo tele ri, Sambo Dasuki ati awon akegbe re ti won ka modi iwa jegudujera owo ti won seto fun rira awon eroja ogun lo si ile ejo okeere ti n ri si idaran, International Criminal Court (ICC). Falana, eni odun metadinlogota (57) lo soro yii nibi ipade kan to waye niluu Abuja eleyii ti Amnesty International se agbeteru re.
Oludije fun ipo gomina ipinle Ekiti lodun 2007 so ninu alaye re wi pe, yato si owo to le ni bilionu meji owo dollar ( $2.1) ti won pariwo ninu awon iwe iroyin, o ni awon owo kan tun wa to ra saaarin Dasuki, Raymond Dokpesi ati Attahiru Bafarawa eleyii ti ko han si opolopo eniyan. O ni apapo owo yii n lo si nnkan bi bilionu mefa owo dollar ile Amerika ($6 billion).

“Awon owo yii ni won seto re lati fi ra awon nnkan ija ogun eleyii ti won fe lo lati koju awon omo Boko Haram ti won yo alaafia Naijiria lenu. Sugbon awon kan gbimo po nipa iwa odaju, adanikanje, oju kokoro, wobia ati imo-tara-eni-nikan inu won lati je iru owo bee mole ti won si n tan awon ara ilu je wi pe awon ti ra awon ohun ija to ye gbogbo fun awon omo ologun ile wa.
Opo won naa ni won si n pada pe awon omo ologun ni ole lasan-bansa ti o le ja latari akitiyan awon soja lati segun Boko Haram ti ko so eso rere,” Falana se lalaye bee.

Falana, eni to je alaga apapo fun egbe oselu National Conscience Party lodun 2011 tun tesiwaju ninu alaye re pelu itara ati ikedun nla bi eni ofo se:” Gege bi omo Naijiria, oro naa dun mi denu egun. Ipenija nla si tun ni isele naa je fun mi gege agbejoro. Nitori mo ti ja fun eto aimoye soja ti won setan lati dajo iku fun latari wi pe won sa loju ija. Oun to mu mi maa ja fun eto won nigba naa ni wi pe, oye ye mi wi pe awon owo ti ijoba n na lati fi seranwo fun awon omo ologun ni ko debi to ye ko de. Ki lo wa de ti won pe iru awon soja wonyii ni ole danu lasan, ti won si tun gbero lati se idajo won pelu iku?”

Falana fi da awon eniyan to wa ni ipade naa lose tokoja loju wi pe, ninu ose taa wayii ni oun yoo te pepe iwe ipejo naa siwaju ile ejo ti n risi idaran ti okeere, International Criminal Court (ICC) lori esun idaran si iran omoniyan.
“Iwa ika owo awon wonyii koja ole jija lasan, idaran si iran omoniyan lesun won. Bi a tile n so nipa awon to wa laaye, n je e tile mo aimoye egberun lona egberun to gbe egberun pon eeyan ti won ti ku latari isele buruku yii, eleyii ti iwa odaju awon eniyan bi meloo kan ti won wa nidi isakoso sokunfa re. Gbogbo awon ti won kowo ti ijoba pese fun rira eroja ogun je pata ni won yoo foju wina ida ofin,” Falana fidi alaye re gunle bee.

Orisun

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

dasuki

Dasuki Tells Court to grant him Bail Or Stop his Trial

Sambo Dasuki, previous national security adviser(NSA), has asked the Federal Capital Territory (FCT) high court to stop his trial for the refusal of the central government to comply with a request of the court granting him bail. In December 2015, Dasuki was granted bail by Yusuf Baba, justice of the FCT high court; while at Kuje jail in Abuja, Dasuki perfected the conditions of his bail, however agents of the Department of State Services (DSS) allegedly whisked him away to ...