Home / Art / Àṣà Oòduà / Gómìnà Kaduna, El-Rufai fi ipò kejì dá Sanusi lọlá láàrin ọjọ́ méjì

Gómìnà Kaduna, El-Rufai fi ipò kejì dá Sanusi lọlá láàrin ọjọ́ méjì

Gómìnà Kaduna, El-Rufai fi ipò kejì dá Sanusi lọlá láàrin ọjọ́ méjì

Ọ̀rọ̀ Sanusi ti fẹ́ jọ ẹni a tì sígbó tó bára rẹ̀ lójú ọ̀nà. A pète pèrò ká dọwọ́ ẹ délẹ̀, pípele ló tún ń pele é síi. Emir ìlú Kano tẹ́lẹ̀, lamido Sanusi tún ti gba oyè mìíràn lẹ́yìn tí Ìjọba Gómìnà Abdullahi Ganduje rọ̀ ọ́ lóyè lọ́jọ́ Ajé.

Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai yàn án gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ káràkátà ní ìpínlẹ̀ Kaduna,(KADIPA).

Lónìí Ọjọ́rú. ọjọ́ Kọkànlá oṣù kẹta ni Gómìnà El-Rufai tún fún Sanusi ní ipò míì.
Olùdámọ̀ràn Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Muyiwa Adekeye ṣàlàyé pé Sanusi ti di alákòóso ìgbìmọ̀ aláṣẹ Fásitì ìpínlẹ̀ Kaduna.

Sanusi rọ́pò Oba Alayé, Malam Tagwai Sambo tó ti wà nípò náà láti ọdún 2005.

Adekeye ṣàlàyé pé Gómìnà El-Rufai fún Sanusi ní ipò ọ̀hún nítorí ipa tó ti kó lórí ètò ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Gómìnà El-Rufai dúpẹ́ lọ́wọ́ Malam Sambo fún bí ó ti gbà pé kí Sanusi di alákòóso ìgbìmọ̀ aláṣẹ Fásitì ìpínlẹ̀ Kaduna tuntun ọ̀hún.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna ti yan Mahammadu Sanusi kejì gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ káràkátà ní ìpínlẹ̀ Kaduna,(KADIPA).

Nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi léde ni wọ́n ti sipe wọn fẹ fi eyi ṣe atunto ẹka to n risi idagbasoke ọrọ aje ni ipinlẹ naa.

Wọ́n fikún un pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí wọ́n mọ pé ìpínlẹ̀ Kaduna yóó rí ohun ribiribi kọ́ lára ọgbọ́n tí Sanusi ní àti òye rẹ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

sanusi

Court declares banishment of deposed Kano emir, Sanusi, illegal, awards ₦10m compensation

Justice Anwuli Chikere of the Federal High Court in Abuja on Tuesday, November 30, declared as illegal, unlawful, and unconstitutional, the banishment of the deposed Emir of Kano, Sanusi Lamido Sanusi to Awe, a remote community in Nasarawa State. Delivering judgement in Mr. Sanusi’s suit, the judge, Anwuli Chikere, awarded ₦10 million compensation to him and against the respondents comprising the police, the State Security Service (SSS), and the Attorney-General of Kano State. She also ordered them to tender a ...