Home / Art / Àṣà Oòduà / Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

Ẹ̀dá tí tó bá sì wà lókè èèpẹ̀ tó ń ṣẹ̀mí, ìrètí kò pin fúnrúfẹ́ onítọ̀ùn, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí fún gbajúgbajà olórin jùjú n-nì, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ó ti le è nàró báyìí lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ tó bá wù ú.

Èyí kò ṣẹ̀yìn kẹ̀ẹ̀kẹ́ ìgbàlódé kan tó ní àwọn èròjà ìrọ̀rùn tó ṣe é yí sí ọ̀tún àti òsì, òkè àti ilẹ̀, ibi tó bá sì wu èèyàn, ló le è yí kẹ̀ẹ̀kẹ́ náà sí.

Yínká Ayéfẹ́lẹ́ , ló kéde pé ó ti rọrùn fún òun báyìí láti rìn pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà lójú òpó Sítágíràmù rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.

Ó fikún un pé ẹlẹ́yinjú àánú kan, tó pé orúkọ rẹ̀ ní Hon Obama Oludare Akande ló fún òun ní kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ayéfẹ́lẹ́ ní “Mo lè dúró kọrin níbikíbi báyìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà, ‘action’ bẹ̀rẹ̀ báyìí, mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Dáre Obama.”

Akọrin Tùǹgbá náà fikún un pé “ìrọ̀rùn dé bá mi gidi báyìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà, Dáre Obama tún ti fún mi ní ìrètí láti rìn padà,.”

Ó wá gbàdúrà fún Aláànú náà pé kò ní mọ ìnira nílé ayé rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ó ti lé ni ogún ọdún tí gbájúmọ́ akọrin ẹ̀mí náà ti pàdánù ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀, tí kò sì leè rìn mọ́ nítorí ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

yinka ayefele

Yinka Ayefele sodun fun awon alaini ati omowewe

Aimoye awon omo wewe ni won pejo si bi ayeye odun keresimesi ati babakeresi ti ile ise redio Fesh FM ti Yinka Ayefele eleyii to waye ni Music House, ile orin Ayefele, to kale siluu Ibadan. Asekagba naa lo waye ni ojo kerinlelogun osu kejila odun (24/12/15) nibi ti awon omowewe ti gba aimoye ebun rele. Leyin ajoyo pelu awon omode ni Yinka Ayefele, eni ti aare ana, Goodluck Jonathan, fi ami-eye M.O.N dalola tun gun ori redio re lo ...