Home / Art / Àṣà Oòduà / Àsepò̩ tó dán mó̩rán wa láarin èmi ati àwo̩n èèyàn O̩yo̩ – Gómìnà

Àsepò̩ tó dán mó̩rán wa láarin èmi ati àwo̩n èèyàn O̩yo̩ – Gómìnà

Èmi àti àwọn èèyàn Ọyọ yóò máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun.. Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé inú dídùn ń ni yoòbá níí mórííya àti pé yiinínú,níí jẹ́ kẹ́ni fẹ́ ṣèmìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti fí èrò ọkàn rẹ̀ hàn pé, ìjọba òun àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò tẹ̀síwájú láti máa fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà fún ìdàgbàsókè àwùjọ.

Makinde sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó péjú síbi ayẹyẹ ìsíde ìdíje ìbọn yínyìn láàrin àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ológun (NASAC), èyí tó wáyé ní iléeṣẹ́ ọ̀wọ́ kejì ológun ti Adekunle Fajuyi tó wà ní àdúgbò Òdogbó Ọjọọ, nílùú Ibadan.

Makinde ní ìnú òun dún fún àyẹsí tí wọ́n fún òun, àti pe, òun àti àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó túbọ̀ máa fọwọ́sowọ́pọọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ológun.
” Mo gbàdúrà pé gbogbo àwọn akópa nínú ètò náà ni yóó se àṣeyọrí, tí ètò náà yóó sì jẹ́ mánigbàgbé fún wọn ní ìpínlẹ̀ Oyo.”

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

apc

Atiku, Saraki, Dogara ati Melaye lè má bó̩ nínú e̩jó̩ jìbìtì Hushpuppi- APC

Atiku, Saraki, Dogara ati Melaye lè má bó̩ nínú e̩jó̩ jìbìtì Hushpuppi- APC Ogbeni Ramoni Igbalode Abbas to je omo Naijiria ti owo te ni ilu Dubai pelu esun jibiti lilu lori ero ayelujara lose to koja ni egbe oselu APC ni owo PDP ko mo nibe. Gege bi atejade to egbe oselu APC gbe jade nipa irinkurin egbe oselu PDP paapaa julo ni asiko idibo odun 2019 to koja. APC ni ki won to so pere, won ti ko ...