Home / Art / Àṣà Oòduà / ÈDÈ YORÙBÁ

ÈDÈ YORÙBÁ

ÈDÈ YORÙBÁ

Èdè Yorùbá ṣe pàtàkì;
Ó ṣe kókó.
Ẹ̀yin ọmọ Oòduà,
Ẹ jẹ́ ká máa rọ́jú s’èdèe wa.
Èdè òǹluko kọ́ l’èdèe Yorùbá.
Èdè tó gba’yì tó gb’ẹ̀yẹ ni.
Àìkọ́mọ l’áhọ́n-ìbílẹ̀,
Ní sábàbí ìwà ọ̀yájú.
Ọmọ yín jí ní kùtùkùtù,
Kò mọ bá a ti ń dọ̀bálẹ̀ kí baba.
Àtikúnlẹ̀ ọmọbìnrin ìwòyí a dìdààmú ńlá.
Ọ̀pọ̀ a lanu gbàù,
Wọn a la’rúkọ m’ágbà lórí.
Háà!
Ó dá mi lójú gbangba,
Èdè àpọ́nlé l’èdèe Yoòbá.
Ọmọ Aládé ló ni ká bọ̀wọ̀ àgbà.
Èdè tí í kọ́ni níwà ni Yorùbá.
Èdè tá a fi í ronú láròjinlẹ̀;
Èdè tó kún mi lójú jọjọ kúkú ní í ṣe.
Gẹ̀ẹ́sì Gẹ̀ẹ́sì șá ni wọ́n fi kó wa lẹ́rú.
Bí Gẹ̀ẹ́sì ‘ò bá ti já gaara lẹ́nu,
Àwọn òpè a ṣe bí tọ̀hún ‘ò nímọ̀.
Bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ tayọ èdè gédégédé.
L’ára ìmọ̀ l’èdèe wà.
Èdè kan ‘ò sì kúkú jù’kan lọ,
Àwa la ‘ò nááníi tiwa.
B’ónígbá bá sì ṣe pe’gbá ẹ̀,
Bẹ́ẹ̀ l’ayé á bá a pè é.
Ọmọ-àlè nìkan ni kì í gb’édè ilé bàbá ẹ̀.
Ó ṣe láraa wa nílẹ̀ yìí.
A gb’òmìnira ìșèjọba,
A ‘à gb’òmìnira èdè.
Èdè Yorùbá ‘ò ní parẹ́.
Àwọn tó gbé e níyì ‘ò ní parun.
Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè ‘ò ní bàjẹ́.
Ẹgbẹ́ Akéwì ẹ kú ișẹ́ takuntakun.
Àbáláyée Nàìjíríà,
Ișẹ́ tó yakin lẹ ń f’ojoojúmọ́ ṣe.
Gbogbo ilé-ișẹ́ rédíò,
Gbogbo ilé-ișẹ́ ìwé-ìròyìn,
Tó ń gbé èdè abínibí lárugẹ,
Iwájú lẹ ó máa lọ.
Gbogbo olólùfẹ́ èdè àtàtà,
Tí í ṣe èdèe Yorùbá,
Ẹ ‘ò ní pàdánù.

Àmín àṣẹ!

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

iwure tooni

#Iwure Owuro Tooni lati enu Kolawole Ifarotimi

Iba Olodumare. Iba Akoda Aye, Iba Aseda Aye, Iba Eniyan. Ekaro, eku ojumon. Ojumon ire gbogbo. Loni, Olodumare yoo silekun gbogbo ire fun o yoo si ti ilekun ibanuje, ekun, ipayin keke pa. Lori jije ati mimun re loni, ooni gbe omi p’ari, oosi niigbe ata pari gbona orun lo pelu. Ina ola re konii joku rebete. Ooni fo loju, ooni ro lapa ro lese. Gbogbo ire ti o ti wo agbole re, koni pada baje. Ooni fi eda re ...