Home / Art / Àṣà Oòduà / Awon olopaa ti mu omo yahoo-yahoo niluu Ogbomoso
Babatunde Abiola Fatai

Awon olopaa ti mu omo yahoo-yahoo niluu Ogbomoso

OlayemiOlatilewa

Owo awon olopaa kogberegbe ti ipinle Oyo ti te onijibiti ori ero ayelujara, Babatunde Fatai niluu Ogbomoso. Tunde to je omo asese jade ileewe Ladoke Akintola University of Technology, eleyii to kale siluu Ogbomosho to wa nipinle Oyo ni won ti mu fun esun orisiirisii to ni i se pelu ole jija ati jibiti  lori ero intaneeti ti won pe ni “yahoo-yahoo”.

 

Tunde to ni oun ti foju bale ejo ri lori esun idigunjale sugbon ti ori pada ko oun yo ni orisiirisii ona ni oun gba lu jibiti lori ero komputa. O ni nigba mi-in, oun le sebi eni ti n wa ololufe lori ero ayelujara, e ni ba ko si oun lowo je gbese. Igba mi-in si ni yii, inu owo ti won ko si banki ni oun yoo fi ona alumonkoroyi fa lo bi igba ti eniyan ba fi owo re aso lori waya.

Awon ohun ti won ka mo Tunde lowo ni akoko ti owo palanba re segi ni milionu meji ati egberun lona irinwo owo naira ile Naijiria (N2.4M), Honda CRV eleyii ti nomba re je KWL 280 CN, oko Nissan Altima eleyii ti nomba re je KJA 963 CA, oko Ford saloon oni nomba  KRD 837 DQ pelu Toyota Camry saloon ti nomba tie je LSR 418 DJ.

Igba ti kondo olopaa dun latari Tunde, ti awon olopaa kogberegbe gbe ibon sagila sibi gogongo orun re, gbogbo ohun ti won ko bi i pata lo bere si ni ka boroboro bi ero ilogi.

“O ti pe ti mo ti n se ise yii, mi o tile le ranti iye owo ti mo ti ri nidi re. E ri sir, ati jale lori intaneeti ko yisi rara o. O gba opolopo suuru. Igba mi-in, ori ikanni ti won ti n yan ore ni maa wa. Ti n si maa wa okunrin tabi obirin ti mo le denu ife ko. Ti mo ba ti ri won de mole, ohun to kan ni lati ri daju wi pe won subu sinu agbami ife mi nipa tite awon oro aladidun ranse si won ati awon ewi ife to ki. Koda, mo tun maa n pe won ta a jo soro daada lori foonu. Leyin eyi ni i maa bere si ni gba owo dollar ti n si maa fi sara rindin”.

Ko tan si be o, Tunde ti a gbo wi pe o un mura lati lo fun eto isinru ilu ti a mo si agunbaniro tun un tesiwaju ninu alaye re. Sebi iya ko toya ni omode ni ko ni daa feni to na un.

“Se e n gbo mi sir? Igba mi-in mo maa fi email adamodi ranse si awon onibara banki bi eni wi pe lati owo banki ni awon leta naa ti wa. Leyin ti mo ba ti gba pin nomba won ati nomba akaunti won ni maa wa lo ogbon alumonkoroyi yahoo-yahoo lati fa gbogbo owo won kuro lowo kan.

Iru owo bayii, mo le ko lati inu banki won ki n fi ranse si okan ninu awon ololufe mi to wa niluu okeere. Eni naa ni yoo wa pada fi ranse simi pada siluu Naijiria nibi”.

Ile ise olopaa ipinle Oyo ni o seni laanu wi pe pupo awon odo iwoyii ni won ri ise ole jija lori ero ayelujara gege bi ona kan pataki lati di eniyan nla lawujo. Won ni ko ba dara ti won ba n lo ogbon ati imo won fun awon nnkan mi-in to se e mu yangan lori intaneeti yato si yahoo-yahoo. Won tun fi kun un wi pe Tunde yoo ma foju bale ejo laipe fun ijiya to to labe ofin ile Naijiria.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb