Home / Art / Àṣà Oòduà / Ewi Toni – 09-04-2016
ewi

Ewi Toni – 09-04-2016

Bisu eni ba ta
Ka fowo booje lo to
Agba ofifo ni dun koro koro
Mo ti reru to domo
Mo si ti riwonfa to ko peteesi
Igba o lo bi orere
Owo aago laye
To ba lowaju a tun pada seyin
Igba lonigba n ka
Ile o si meni n teun
Agemo ti n tele yoyooyo
Iku n foga sara rindin
Se opolo ti n janra mole
Nni ‘ku o ni san?
Ore se jeje ile n mi
Boo ba gbagbe
Je n ran o leti
So o ranti Kaaruna olowo aye?
Abi o gbagbe Farao onipo atata
Gbogbo pakaleke e won
Ani gbogbo fufulenge ki lo wa dure le?
Baa ba n fapa ajanaku n sanyan
Baa ba n fitan ogongo joka
Bo ba buse gada to buse gede tan
Dedengbo ni o pada fi gbogbo wa yata
Gbogbo mo le goke mo le so
Gbogbo fufulanga fufulanga
Afemi afemi
Nijo iku ba de laapon a pin
Bi’ya re ba lowo bi olowo aye
Ti Baba n fagbo bolojo moguro
O je ranti pasan bansa laye
Gbogbo gulegule o kojaa saare
Ojo tifa a peran
Topele yoo sebe oyinmolaka
Tomo Awo o ni le gbokele nko?
Se ipa o wa ni pin?
Feso jaye ore
Boo ba lowo lowo
Seranti alaini
Boo ba n gbokele atata meta lojumo
Ranti eni n fagbara kaka jeekan
Se o si wa mo wi pe ilakaka re ko rara
Kadara o ku fagba
Atila o fa girigiri asedanu ofo
Ki lo ha de taa kuku fowo wewo
Ka fese wese
Kaye o le ye mutumuwa
Opo oro o kuku k’agbon
Yooba ni:afefe ni n baa lo
Ka ranti atubotan
N lorin ti mo n diju magbari n ko.
……………
…………….
O to ojo meta taa rira wa,bi o nidii obinrin o ni je
kumolu,Eyi to ba si je kumolu a je wi pe…………
tor e seun eyin omoran ti n moyun igbin E ma
binu si mi. ire o.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

ewi

Video: Ewi Rendition

@oluwavalu: We made this video for U.K based musical Artiste @caleb_kunle It was shot during the Covid-19 lockdown in Oworo and i am proud at what we were able to achieve given the little resources at hand then. I Directed this and was assisted by @coolestafrican_kid and @mrbukolajimoh who also iss the D.O.P and Editor of the project. @panafricanmusic just published the video on their YouTube page, go follow the link on @calebkunle‘s Instagram Bio to view the video. Shout out to my main people all ...