Home / Art / Àṣà Oòduà / Àsepò̩ tó dán mó̩rán wa láarin èmi ati àwo̩n èèyàn O̩yo̩ – Gómìnà

Àsepò̩ tó dán mó̩rán wa láarin èmi ati àwo̩n èèyàn O̩yo̩ – Gómìnà

Èmi àti àwọn èèyàn Ọyọ yóò máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun.. Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé inú dídùn ń ni yoòbá níí mórííya àti pé yiinínú,níí jẹ́ kẹ́ni fẹ́ ṣèmìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti fí èrò ọkàn rẹ̀ hàn pé, ìjọba òun àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò tẹ̀síwájú láti máa fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà fún ìdàgbàsókè àwùjọ.

Makinde sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó péjú síbi ayẹyẹ ìsíde ìdíje ìbọn yínyìn láàrin àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ológun (NASAC), èyí tó wáyé ní iléeṣẹ́ ọ̀wọ́ kejì ológun ti Adekunle Fajuyi tó wà ní àdúgbò Òdogbó Ọjọọ, nílùú Ibadan.

Makinde ní ìnú òun dún fún àyẹsí tí wọ́n fún òun, àti pe, òun àti àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó túbọ̀ máa fọwọ́sowọ́pọọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ológun.
” Mo gbàdúrà pé gbogbo àwọn akópa nínú ètò náà ni yóó se àṣeyọrí, tí ètò náà yóó sì jẹ́ mánigbàgbé fún wọn ní ìpínlẹ̀ Oyo.”

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Ikán parapọ̀, ikán mọ ilé; èèrùn parapọ̀, wọ́n mọ àgìyàn; àwọn oyin parapọ̀, wọ́n mọ afárá.

Òwe Tòní

Ikán parapọ̀, ikán mọ ilé; èèrùn parapọ̀, wọ́n mọ àgìyàn; àwọn oyin parapọ̀, wọ́n mọ afárá. TranslationThrough collective labour, termites erected majestic cities, ants built fortified strongholds, and bees fashioned efficient honeycombs. WisdomUnity is strength, and together, we achieve more! A kòní sin wọn wáyé Laṣẹ Olodùmàrè. Àṣẹ! A ku Ojúmọ́