Home / Art / Àṣà Oòduà / Igbeyawo Ooni Ile-Ife fo yangayanga?
Igbakeji Orisa

Igbeyawo Ooni Ile-Ife fo yangayanga?

*Oba Ogunwusi n mura lati se igbeyawo tuntun

 

Lose to koja ni awon aheso oro kan be sile nigboro eleyii to ti bere si ni mu awuyewuye lowo bayii. Lara awon oro naa ni eyi ti n wi pe, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi ti ko aya re, Olori Adebukola Ogunwusi sile. Ede-aiyede to be sile laaarin loko-laya naa lo tun pada bureke leyin ti won jawe oye le Oba Ogunwusi lori.

Bi o tile je wi pe gbagbaagba ni Olori Bukola le mo Oba Ogunwusi lojo ti Gomina Aregbe gbe opa ase le e lowo, sibesibe, ohun ti a gbo ni wi pe, ikunsinu ti be sile laaarin ololufe meji naa saaju akoko naa. Wahala to wa laaarin loko-laya yii ni idile mejeeji si ti gbiyanju ki won pari sugbon ti gbogbo akitiyan naa jasi otubante, ofo ojo keji oja.

Gege bi akiyesi awon eniyan, won ni lati igba ti won ti bura fun Oba Ogunwusi ni won ko ti ri i pelu aya re mo, eleyii to mu ifura dani wi pe, oseese ki awon aheso oro naa ni otito ninu.

Nibayii, omobirin tuntun ti won lo se e se ko je aya oba tuntun laaafin ni Omidan Wuraola Otiti Zynab Obanor to wa lati agboole Oluyare to wa ni adugbo Iremo ni ilu Ile-Ife.

Sugbon sa, ilu Benin ni iran awon omo naa ti se wa si ilu Ile-Ife. Omidan Wuraola mole gboo bi ojo, awo ara re si tutu minijojo bi eja arogidigba lodo. Ewa omidan naa lekenka to bee gee, eleyii ti opo awon eniyan gba wi pe yoo tun bu iyi kun Ooni Ojaja gege bi oba to gbo faari oge sise.

http://www.olayemioniroyin.com/2016/02/igbeyawo-ooni-ile-ife-fo-yangayanga.html

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

ooni

Ooni And His Olori, Silekunola Naomi Ogunwusi Welcome Aremo

Ooni of Ife has announced the birth of his first child with Olori Silekunola – a baby boy, NaijaCover Reports. He said the Prince was born today, November 18, 2020. A statement via his official Instagram account reads: “To God be the glory great things he has done. Hearty congratulations to the entire House of Oduduwa and Olori Silekunola who today birthed a Prince to the Royal throne of Oduduwa.Mother and child are doing well to the glory of God ...