Home / Art / Àṣà Oòduà / Awon ojogbon fi oye dokita da Tinubu lola
tinubu

Awon ojogbon fi oye dokita da Tinubu lola

Oloye agba egbe APC, Asiwaju Ahamed Bola Tinubu ni won ti foye dokita dalola bayii ni ogba Yunifasiti tiluu Abuja. Idalola agba oloselu to je gomina ti yoo je sikejila (12th) nipinle Eko lo waye ninu ayeye ikojade awon akekoo gboye ileewe naa. Ayeye yii to waye yii ni i se igba ogun ti ileewe naa yoo ma se ayeye ikojade awon akekoo gboye lati igba ti wan ti se idasile re.

Ti e ko ba gbagbe, laipe yii ni iwe iroyin SUN tile wa fi ami eye “Man of the Year” da Tinubu lola latari akitiyan ati akikanju re lati mu igba yipada fun ile Naijiria lagbo oselu. Oloye Tinubu, eni ti won fun loye Jagaban niluu Borgu to wa nipinle Niger, ko sai fi idunnu re han bi awon alase Yunifasiti Abuja se gbe aponle ati iyi oye dokita naa fun un. Eleyii to tun fi da won loju wi pe, oun ko ni duro ninu akitiyan lati mu igbe aye awon eniyan larinrin ju ateyinwa lo.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

tinubu

Èmi àti Olure̩mi yege àjàkálè̩ àrùn covid-19 – Tinubu

Asiwaju agba fun egbe oselu APC, Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu ni oun ko ni arun ajakale coronavirus bi gbogbo eniyan se n gbee poori enu. O ni awon kan ni oun ti wa ni igbele olojo merinla pelu Oluremi. Awon kan tile ni oun ti ko aisan naa ni eyi ti o mu ki oun ati Oluremi se ayewo arun naa.Asiwaju ni ko je dandan pe ti eni to ba wa ni egbe eniyan ba ni arun, eni naa gbodo ...