Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifa naa ki bayi wipe
opn ifa

Ifa naa ki bayi wipe

| |   |
| |   |
| |  | |
| |   |

YORUBA VERSION: Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isimi oni, emin wa yio se pupo re laye o ase.
Odu ifa OKANRAN IRORUN lo gate laaro yi, ifa yi fore Omo gidi ati ire irin ajo lo si ilu alawo funfun fun eniti odu ifa yi ba jade si, ifa ni yio bi awon ologo ati olokiki omo ifa ni ki o rubo.
Ifa naa ki bayi wipe: Kasooto kasooto titi ka jaye pe o san ju ka sebita ka wa laye ka lowo lowo bi oloro jingin a difa fun olokun ajaro okoto lojo ti yio fi gbogbo omo re bi funfun, won ni ko karale ebo ni ki o wa se obi meji, eyele funfun balau, pakata ekuru, agba otin ati igba ewe ayajo ifa olokun ajaro okoto kabomora o rubo won si se sise ifa fun, ko pe ko jina olokun ajaro okoto roole omo ni bibi, o wa fi gbogbo omo re bi funfun ninini gbogbo won si yan won si yanju won lokiki olokun wa njo o nyo o nyin awo awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo omo ti a ba bi ni yio yan ti yio yanju o, awon omo wa yio je ologo ati olokiki Omo, ako ni bawon bi papanlagi omo o, eledumare yio si gbohun awon ti won nfoju ekun nserahun omo, ire oke okun yio si je tiwa o aaaseee. ABORU ABOYE OOO.

 

English Version – Good morning my people, how was your night? Hope it was enjoyed. I wish you all a vibrant Sunday.
It is OKANRAN IROSUN corpus that revealed this morning, ifa foresee blessing of good child/children and travelling to the town of white people for whoever this corpus revealed out for, ifa advised him/her to offer a sacrifice very well.
Hear what the corpus said: To tell the truth and live long is better than to be falsify and been enjoying inside a lot of money it cast divined for olokun ajaro okoto when she would give birth to white children, she was advised to offer sacrifice so that all her children could be prosper and successful in life two kola nuts, white pigeon, ekuru funfun, gin and ifa leaves and she complied, aftermath she gave birth to white children and they all became famous and successful in life, she started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
My people, I pray this morning that all our children will become successful in life, we shall never give birth to mischievous child and all peoples that were looking unto the eyes of God for child will be answered, we shall receive the blessings of abroad

Faniyi David Osagbami

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Fẹ́mi Akínṣọlá Ṣe aifẹsọ kebosi,lai rẹni jo o,ati pe n ta o ba fẹ o bajẹ,o ni bi o ṣe yẹ ka ṣe e,eyi lo bi atunse abẹnu lati fopin sawuye wuye to waye latari aawọ to suyọ laarin awọn onisese ati awọn ẹlẹsin meji ti o ku(Kitẹẹni ati Musulumi).Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.Kareem, ẹni to soju ...