Home / News From Nigeria / Breaking News / Odu Okanran Oyeku
baba ifa

Odu Okanran Oyeku

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o a sin ku isimi opin ose olorun eledumare yio fi ibunkun sori ise wa o ase.

Odu OKANRAN OYEKU lo gate laaro yi, odu ifa yi gba eniti o ba jade si niyanju wipe ki o se etutu daradara ki o bo oke iponri re, ifa ni akapo yi njaye inira kaka koko ifa ni gbogbo adawole akapo yi ko yori si rere debi wipe gbogbo adura to ngba awon aye lo nfi owo ntele adura naa ti won ko je ki o je itewogba lodo eledumare, ifa ni sugbon bi akapo yi ba le bo oke iponri ire gbogbo ati aye irorun yio de fun-un.
Ifa naa ki bayi wipe: Ejo lawo ilare a difa fun olofin larimo aye lojo ti nfojojumo njaye inira kaka koko, gbogbo ebo ti olofin ba se ki nfin beeni etutu re ki nda ko rije ko rimu gbogbo adawole re ko ki nyori si rere won ni ko karale ebo ni ki o wa se obi meji, eja aro tutu meji, igba Omi tutu ati sile mejilelogun owo aidin olofin kabomora olofin rubo won si se sise ifa fun, ko pe ko jina ni irorun ba de ba olofin, o wa bere sini nrije o nrimun adura re bere sini ngba ko wa jaye inira kaka koko mo o wa njo o nyo o nyin awo awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa. O wa fiyere ohun bonu wipe; nje o mato akoko lati ko wa ro wa o aro de o Omo oni jeeje aro.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ako ni jaye inira kaka ako sini jaye inira koko olorun eledumare yio bawa tu orile ede naijiria se gbogbo adawole wa yio maa yori si rere adura wa yio si maa je itewogba lodo eledumare, ao bere sini maa gbe igbe irorun, ayo ati alaafia lagbara Orunmila mimo alagbawi aaaseee. ABORU ABOYE OOO.

 

English version
Good morning my people, how was your night? Hope it was splendid, wishing you all a beautiful weekend. May abundant blessings of God be upon our works and businesses ase.
It is OKANRAN OYEKU corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice so that he/she will never experience hardship in his/her life, ifa said the way of his/her living was very tight and tough but if he/she could offer sacrifice for oke iponri things will turn out well again for him/her.
Hear what the corpus said: The snake is the priest of ilare cast divined for olofin larimo aye when his life was tough and rough, he did prayers but it was not accepted, everything was very hard for him to do, he was advised to feed oke iponri with two kola nuts, two fresh cat fish, water and twenty-two shillings and he complied, aftermath things were easy for olofin, he didn’t live in agony and his prayers were been accepted he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa, while ifa was praising God, he started singing the song of ifa that; it is now a time to be easy for me, the “aro” has come the offspring of onijeeje “aro”.
My people, I pray this morning that we shall never live in hardship anymore, all our prayers will now be accepted, God in his mercy will see us through in this country and we shall be living conveniently, peacefully and joyfully ase.

Faniyi David Osagbami

 

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...