Home / Art / Àṣà Yorùbá / Ògún lákáayé .

Ògún lákáayé .

Ọ̀wọ́nyán rosùn porogodo lóso, Agogo ńlá ni wọ́n fi ń fọ́ri fálágbára mu, Àtàtà ńlá ni wọ́n fi ń fọ yíìrí mọrọ̀, Adífáfún Ògún tíń gbógun lọ sí Ìgbòmẹkùn-eséji, ẹbọ lawo níkóse, Ògún ló sẹbọ sètùtù lówá kóre dé ìtùtúrú

Ògún lákáayé
Oníjà oòle
Ẹjẹmu olúwọnran
Adìgìrì rebi ìjà
Koríko etídò
tíírú mìnìmìnì
Sékélé ni ń o ma rọ̀bẹ
ní pópó iyemakin
Sàgàlà lọ̀bẹ ìrè
Ọ̀bẹ ìrèmògún di ogójì
Ọ̀bẹ ìrèmògún di ọ̀wọ́ngógó
Ọmọ rọ́wọ́rọ̀wọ̀rọ́wọ́
Bí Alágbẹ̀dẹ́ kòbá rọ́wọ́
Ọmọ fínnáfìnnàfínná
bí Alágbẹ̀dẹ kòbá fínná
Tọlọ́kọ́ taládàá ni yóò mọ sùn sọ́nà oko

Ògún yeeeeeeeeeeeeeeeeeeeeeee

Send Money To Nigeria Free

About Awoyemi Bamimore

x

Check Also

Odu Ifa

Owonrisogbe – Ifá Naa Ki Bayi Wipe: Biijo biijo…

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku orire osu Ògún tuntun to bawa layo ati alaafia, osu naa yio sanwa sowo, somo, sile kiko, moto rira, ire oko/aya ati aiku baale oro yio je tiwa, Ògún lákayé yio lana funwa o Àse. E jeki a fi odù mímó Owonrisogbe you se ìwúre ibere osu yi.Ifá naa ki bayi wipe:Biijo biijoBiayo biayo a difa fun agbado lojo ti nroko alere odun, won ni ko ...