Home / Art / Àṣà Yorùbá / Olojo Ibi Toni
olojo

Olojo Ibi Toni

Mo layo lati so fun yin wipe oni ni ojo ibi Alagba Oluwakayode Olamilekan Adekoya Ijeni ti won je okan gboogi ninu ebi Omo Yoruba.
Okan pataki ni won je lara awon majekobaje ilu yi, oloye nla niwon laafin Olumoye. Balogun igbomekun oye ni mo nke si.
OBA lori Ogun, mo ki yin e ku ayo oni, e o se pupo re laye ninu alafia ara ati ibale okan.

Ni oruko Oluwa e o ni ba won na oja warawara nile aye beeni e o si ni dagba yeye, gbogbo ohun rere ti n mu’le aye rorun fun eda ni Eledua yoo fi jinki yin. E o gbo, e o to, e o fewu pari, e o ferigi jobi, e o gbele aye sohun rere bi o ti wa wu ki e pe to laye e o ni f’oju mo saare omo lase Edumare.
Kabiyesi ati awon Oloye ati gbogbo ebi Omo Yoruba Atata pata nileloko nki yin wipe IGBA ODUN, ODUN KAN NI O..

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

iwure

Iwure Toni: Orí Ma Jẹ Kí Ire Tí Moní Kó Pẹ̀dí ..

Ifá ma jẹ kí ire tí moní kó pẹ̀díOrí ma jẹ kí ire tí moní kó pẹ̀díOlú ọ̀run ma jẹ kí ire tí moní kó pẹ̀díNítorí ata wẹẹrẹ kín pẹ̀ dí nínú ọbẹ̀ ata wẹẹrẹ Mo sé ní iwure fún orí kọ̀ọ̀kan wa ní ojúmọ́ tòní wípé gbogbo ire tí kálukú wa bá kójọ kò ní pẹ̀dí mọ́ wa lọ́wọ́ o láṣẹ Olódùmarè. Àsẹ