*Won gun un lobe lorun pa ni
Ogbeni Ogunlaja ti enikan sadeede gun lobe legbe orun leyin irun alaasari lagbo wi pe o n mura lati rekoja lo si ilu Faranse pelu awon omo re meji ati iyawo re lati lo jegbadun opin odun mo odun tuntun to n bo lona.
Gege bi iwadii ti OLAYEMI ONIROYIN ri kojo, okan pataki omo egbe awako (NURTW), eka ti Marina ni Ogbeni Ogunlaja je. Bakan naa la si gbo wi pe rugudu kan an sele lowo leka egbe won naa eleyii ti won pinnu lati yanju nibi ipade gbogboogbo olosoosu to ma n waye ninu egbe naa.
Nibi ipade yii naa ni won wa ki Ogbeni Ogunlaja to jade lo josin fun oba Allah ko to di wi pe ika eniyan kan pinnu lati ran sodo oba Allah patapata nipa fifi obe oloju meji, elenu sonso, eleyii ti won tibo egbe orun re. Ogbeni Ogunlaja ko ku loju-ese, o n japoro nile ninu agbara eje to ti kun gbogbo ile ko to re ni sun mo o.
Iyawo oloogbe naa salaye fun awon olopaa wi pe ohun ti oko re so gbeyin lori foonu ko to lo si mosalaasi ni wi pe, wahala ti won ba awon yanju naa ko ti kesejari.
“Lojo Alamisi to koja yii, oko mi gba ipe ori foonu lati odo okan lara awon omo egbe onimoto lati ran an leti ipade olosoosu won ti won maa n se.
Oko mi sare woso bee lojade nile ni nnkan bi ago kan osan-an. Igba to se die mo pe e, o si fi damiloju wi pe oun ti debi ipade naa. Ohun ti oko mi tun so ni wi pe awon oro ti won ba oun so ko ye oun rara. O ni awon owo kan ti oun ko modi ni won ni ki oun maa se isiro re. O si so fun mi wi pe laipe, oun yoo fi ipade naa sile lati lo kirun,” aya Ogunlaja se lalaye bee.
Leyin eyi ni won pe aya Ogunlaja wi pe oko re wa losibitu. Igba ti yoo fi de osibitu ti won gbe lo l’Abule-Egba, won ni won ti taari re lo si Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH) to wa n’Ikeja nigba ti agbara osibitu ti won koko gbe lo ko kaa. Sugbon ki won to de LASUTH, ogbeni Ogunlaja ti padanu opolopo eje ninu inira nla eleyii to si mu je ipe Olorun laipe ojo.
Aya Ogunlaja ti bere si ni rawo si awon agbofinro lati ma je ki iya naa je e lajegbe nipa sise awari ika eniya to seku pa oko re.
Gbogbo igbiyanju OLAYEMI ONIROYIN lati kan si alarinna ile ise olopaa ipinle Eko lori oro naa lo jasi pabo.