Home / Art / Àṣà Oòduà / Odo Iwoyi: Oro Kan Ni Nrumi Loju Ti Mo Si Nilo Amoran Lori Re.
odo iwoyi

Odo Iwoyi: Oro Kan Ni Nrumi Loju Ti Mo Si Nilo Amoran Lori Re.

E ku ile ni a n k’ara ile, e ku abo ni a n k’ero ona, ti a ba ti rira eni tipe, e ku atijo ni a ma nki ara eni.
Mo ki gbogbo ebi Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi, beeni mo ki eyin ololufe eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi, e jowo e ma fi se ibinu wipe o to ojo meta lori eto yi, somoni lo lotinrin die. Ju gbogbo re lo, a dupe lowo Aseda ti o je ki a tun gburo ara wa.
Ni bayi eto wa ti pada de, gege bi e ti mo lori eto yi ni a ti maa n gba awon Odo wa lamoran lori oro ti o ru won loju, se e si mo wipe ibi ti a ti n se itoju alaisan ni a ti n toju ara eni? Bi a ti n gba awon ti oro kan lamoran beeni opo wa pelu n kogbon latara awon amoran eyin oloye eniyan.
Gege bi ise wa atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sunukun woo, ki a si gba won lamoran bi o ti ye. E MAA BA WA KALO:-
“Olootu mo ki yin e ku ojo meta o, beeni mo ki gbogbo awa ololufe eto Odo Iwoyi wipe ile ati ona enikookan wa ko ni daru lase Edumare. E jowo olootu oro kan ni nrumi loju ti mo si nilo amoran lori re.

 
Eni odun metadinlogbon ni mi bayi, odun ti o koja lo yi ni mo setan ni ile eko ifasiti, ile hausa ni mo si ti Ka eko ifasiti mi, ipele ikeji ni mo wa ni ile eko ifasiti ni odun yen loun ni mo pade omokunrin kan, arakunrin yi da mi laamu lopolopo sugbon n ko kobi ara sii, nitori hausa ni arakunrin na, sugbon nigba ti idamu arakunrin yi po, ti awon ore mi pelu si fenu sii wi pe boya ki n gba arakunrin na laye, ki n wo ise re fun igba die, beeni mo gba oro si won lenu ti mo si gba fun arakunrin na, bayi ni a bere sii ba ere ife wa bo.

 
Hmmm ase looto ni wi pe ko si eya kan laye ti eniyan rere ko si, koda ti n ko ba ni paro arakunrin yi se eniyan, laarin awon okunrin ti mo ti n ba pade ti won je Yoruba gan nko ri eniyan bi arakunrin yi.
Iranlowo, atileyin ati amoran arakunrin yi wa lara ohun ti o mu mi se aseyege nile eko na. Arakunrin yi si se ileri fun mi lati fi mi se iyawo ile re ti okan emi pelu si ti bale wipe mo ti debi ayo mi, sugbon o wa ya mi lenu wi pe awon obi ti o bi mi gan ni won fe dabi elenini fun mi bayi.

 
Baami ati maami a ti maa da mi laamu tipe wi pe awon fe ri afesona mi, beeni mo si mu arakunrin yi wale ni ojo abameta ikeji seyin. Ni kete ti arakunrin yi ti wole ti awon obi mi rii ni mo se akiesi wipe inu won ko dun bi o ti ye, looto ko han si arakunrin yi sugbon mo se akiesi nitori mo mo awon obi mi mejeeji daradara.
Opolopo ibeere ni baami bi arakunrin yi, eyi ti o si daun leseese, sugbon bi arakunrin yi ti setan ti o si pada sibi ti o ti wa ni baami ati maami pe mi, ti baami si tenu bo oro wipe:-
“Woo arabinrin toba je emi ni mo bi o, o koi ti r’oko o tori eyi ti o mu wa yi kii se oko o, abi nibo ni o ti gboo ri ninu itan wipe aboki wa nile wa? Boya mola si wa ninu iran iya re emi ko mo, laduru gbogbo okunrin ti o wa nile Yoruba o ko ri okan nibe ayafi omo yanmirin? Woo emi o lowo nibe o, ko ya tete wa nkan miran se o”
Bi baami ti danu duro ni mo daun wi pe, sugbon dadi sebi won ni ife ni o se pataki ninu oro igbeyawo, emi ati arakunrin yi si ni ife ara…..
N koi ti dele oro mi ti maami fi gba oro mo mi lenu, ti won si wipe :-
“Gbe enu re soun, iru ife buruku wo niyen, Olorun o ni je ki o ni ife boko haramu, abi awon ti won nse boko haramu ko ni eyi? ”
Ni mo daun wipe haa maami oko temi kii se boko haramu o, ni maami na owo mu kini ti a fi maa n tan ero amohun maworan ti o wa lori tabili ti won si wipe ti mo ba tun soro awon yoo Soo lu mi. Beeni mo dake ti mo si n wo won niran. Opolopo oro ni maami tun so leyin eyi ti won ti so saaju, nse ni maami nwipe bawo ni n o ti mu okunrin ti awon ko gbede re ti ko si gbede tawon wa gege bi oko, looto arakunrin yi ko gbo Yoruba sugbon oyinbo ja gere lenu re, boya nitori maami ko gboyinbo taara ni oro na se wa Ka won lara to be, nitori won ko ni anfani lati ba arakunrin na soro lojo ti o wa sile sugbon baami baa soro daradara. Maami tun wi pe se bi won ti n ki ana ni ile Yoruba ni arakunrin yi se ki awon nigba ti o wole yi? Gbogbo awon awawi keekeke wonyi ni maami n wi ti won si fe fi ba ojo ola temi je, sebi die die ni eniyan yoo maa mo nkan, emi ro wi pe nse ni o ye ki awon obi mi maa to awa mejeeji sona dipo iwa ti won n hu yi.
Oro yi ti wa su mi bayi tori awon obi mi o setan lati gbo alaye kokan lenu mi ayafi ki n mu okunrin miran ti o je Yoruba wa, mo si ro wi pe, ife ni ohun ti o se pataki julo ninu oro igbeyawo, e dakun ti mo ba mu Yoruba wale ti eni na ko si ni ife mi nko? Afi bi eni wipe awon obi mi kan fe ba ojo ola mi je tori won ni ti eniyan ba ti si ese gbe ni akoko a nwoko tabi aya asise ayeraye ni. Iyen ni mo se to eyin oloye eniyan wa ki n ma ba siwa hu, tori nko fe je omo ibanuje fun awon obi mi beeni nko si fe ba ojo ola mi je lati te won lorun, eyin oloye eniyan ki ni ki n se bayi? Abi ki ni o buru ninu ki n loko nibi ti o wu mi? ”
Hmmm Oro Olorun ida oloju meji, bibeli wipe “EYIN OMO E MAA GBORAN SI AWON OBI YIN LENU” beeni o tun wipe EYIN OBI E MA SE MU AWON OMO YIN BINU, e jowo ti awon obi omo yi ba wa yari kanle bayi se kinse wipe won ti mu omo won binu ree? Beeni ti omo ba setan ati se ife inu re, nje kii se aigboran si obi ree?
Eyin ojogbon ki ni ki arabinrin yi se ni ikorita ti o wa yi gan ati pelu ki ni o buru ninu ki a fe elede miran gege bi aya tabi oko? Oro ree o eyin oloye eniyan.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti