Home / Art / Àṣà Oòduà / Oríkì ìbejì

Oríkì ìbejì

Oriki Ibeji:
Wíníwíní lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
Ẹdúnjobí,
ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé,
Ó bé sílé alákìísa,
Ó salákìísà donígba aṣọ.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.

Bi Táyélolú ti nló ni iwájú,
Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
Táyélolú ni àbúrò,
Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò,
B’ayé dára , bi ko dára

O tọ́ ayé wò,
Ayé dun bi oyin
Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín,
Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú.

Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l’ọ́mọ,
èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w’ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo…

Àmín àṣẹ

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti