Home / Art / Àṣà Oòduà / Ẹlẹ́buùbọn gba ìpàdé àwọn ẹlẹyẹ ẹ̀ka ti Ọ̀ṣun
eleye ika

Ẹlẹ́buùbọn gba ìpàdé àwọn ẹlẹyẹ ẹ̀ka ti Ọ̀ṣun

Ẹlẹ́buùbọn gba ìpàdé àwọn ẹlẹyẹ ẹ̀ka ti Ọ̀ṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbajúgbajà onímọ̀ nípa ìṣègùn ìbílẹ̀ nílẹ̀ ẹ Yorùbá, tó tún jẹ́ Olóyè Àràbà nípìńlẹ̀ Oṣun.

Ifáyemí Ẹlẹ́buùbọn ti gba ìpàdé ńlá àjọ̀dún ayẹyẹ àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn oṣó àti àjẹ́ ní ìpínlẹ̀ Oṣun.

Níbi ìpàdé yìí ni onímọ̀ ìṣègùn ìbílẹ̀ ti fi ọ̀rọ̀ léde pé ìtàjẹ̀sílẹ̀ léwu púpọ̀ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yìí.

Nígbà tó ń bá ìpéjọpọ̀ náà ṣọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ ọse, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ti ẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú àwọn àjẹ́ àti oṣó ìpínlẹ̀ Oṣun, Ẹlẹ́buùbọn rọ Ìjọba

àpapọ̀ láti tètè wá wọ́rọ́kọ́ fi ṣàdá lórí ìpànìyàn tó ń wáyé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó ní kí wọ́n ṣe èyí kí Ìbínú Ọlọ́run tó sọkalẹ s’órí orílẹ̀-èdè.

Gẹ́gẹ́ bí onifa yìí ṣe sọ ọ, wọ́n gbọdọ̀ tọwọ́ọ lemọ́ lemọ́ ìpànìyàn tó ń wáyé níhàa Àríwá orílẹ̀-èdè yìí àti ìpànìyàn fi ṣòògùn owó níhàa Gúúsù bọ aṣọ, kí àbámọ̀ má baà gbẹ̀yìn rẹ̀.

Ó gba àwọn onímọ̀ ìṣègùn ìbílẹ̀ nímọ̀ràn láti mọ̀ dáadáa nípa ẹ̀sìn wọn, láti má fààyè gba ọ̀rọ̀ tí kò bá ohun tí wọ́n ń ṣe mu àti pé, kí wọ́n wà ní ìdúró déédé àti ṣíṣe òdodo pẹ̀lú àwọn èèyàn láti jẹ́ èèyàn ire láwùjọ.

Ó ní gbogbo ẹ̀dá alààyè ló ní ẹgbẹ́ ọ̀run kan tàbí òmíràn tí wọ́n ń ṣe. Ó sì tẹnu mọ́ ọ pé mímọ ẹgbẹ́ ẹni dáadáa àti ṣíṣe ìfẹ́ inú wọn máa ń ran ìrìnàjò ẹ̀dá láyé lọ́wọ́.

“Iye ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìfini sẹ́ṣó owó ní Nàìjíríà ń kọ ni lóminú.

Kí Ìjọba ní gboogbo ìpele mú òpin wá sí èyí, kí Elédùwà tó rọ̀jò ìbínú Rẹ̀ lé orílẹ̀-èdè lórí.

Mo rọ ẹ̀yìn àjẹ́ àti oṣó kí ẹ máa gbé ìgbé ayé òdodo èyí tí wọ́n mọ àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ fún, ki ẹ sì jẹ́ kí ẹ̀ṣìn àwọn baba ńlá baba wa ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín padà, torí òhun nìkan ló leè dáàbò bo irú èèyàn tí ẹ jẹ́ l’ágbàáyé”.

Nínú ọ̀rọ̀ olùdarí ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Oṣun, Olóyè Arábìnrin Oyelola Ẹlẹ́buùbọn sọ wípé pàtàkì ìpàdé náà ni láti fihan gbogbo àgbáyé pé jíjẹ́ oṣó tàbí àjẹ́ kìí ṣe nǹkan ibi bí àwọn ẹlẹ́ṣìn ṣe ń wò ó, ó ní bí wọ́n bá lo àwọn agbára tó wà nínú rẹ̀ dáadáa, ó leè yí gbàgede ìmọ̀ ẹ̀rọ orílẹ̀-èdè kan padà fún ìdàgbàsókè.

Láfikún, ó rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti ní ìfarajìn nínú ìlú pẹ̀lú bí ohun gbogbo ṣe le tó àti pé rínrìn déédé àti ṣíṣe òdodo ni kó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ wọn ní gbogbo ìgbà.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Araba Ifayemi Elebuibon

Araba Araba Yemi Elebuibon reveals the Taboo he Broke

Yorubaland’s foremost Ifa priest, actor and also the Araba of Osogboland, Ifayemi Elebuibon recently turned 70 and gave an interview to Tribune newspaper . He spoke on the origins of his name, the circumstances around his birth , hardships in his early  life and quite a bit more.   He told Tunde Busari that although it was a taboo for him  to  attend school ( learn English/ gain Western education, presumably because he was an Ifa apprentice at the time) , ...