À nì sẹ́, dan dan l’óúnjẹ ọfẹ fún ọmọ rẹ ,kíláàsì kínní dé ìkẹta alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀- Ìjọba àpapọ̀
Iléeṣẹ́ tó wà fún ìpèsè ohun ìrànwọ́ nílẹ̀ wa ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí nínú àtẹjáde kan tó fisíta lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀.
Àtẹjáde náà ní gbogbo Ìpínlẹ̀ tó wà ní Nàìjíríà ni wọ́n ti rọ̀ láti lo gbogbo àkọsílẹ̀ tó wà nkàáwọ́ wọn láti tọ ipaṣẹ̀ ilégbèé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà láwọn Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Ìjọba.
Ṣùgbọ́n yàtọ̀ sí bó ṣe ń wáyé tẹ́lẹ̀, Ìjọba ní àwọn òbí àti alágbàtọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lẹ́tọ̀ọ́ sí oúńjẹ ìjọba náà, ni wọn yóó gbe fún.
“Kìkìdá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní kíláàsì kínní sí ìkẹta láwọn Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Ìjọba nìkan, ni yóó jẹ àǹfààní ìpèsè oúnjẹ náà, èyí tí yóó kan ojúlé bílíọ́nù mẹ́ta ó lé díẹ̀, 3,131,971.”
Lára àwọn èròjà oúnjẹ tí Ìjọba yóó pín fún ìdílé akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí oúńjẹ náà ni, àpò ìrẹsì oní kílógíràmù márùn-ún (5kg), àpò ẹ̀wà oní kílógíràmù márùn-ún bákan náà, òróró ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mìlílítà 500ml, epo Pupa oní ọ̀tàlélẹ́ẹ̀dẹ̀gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá mìlílítà, 750ml, iyọ oní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílígíràmù, 500mg, ẹyin ẹyọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti tómátò lílọ̀ lúbú-lúbú oní mílígíràmù ogóje, 140gm.
Ìjọba ní àpapọ̀ gbogbo owó àwọn èròjà tí wọ́n fẹ́ pín fún àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí oúńjẹ náà, jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti igba Naira, N4,200.
“Ìgbésẹ̀ pínpín ìwé ẹ̀tọ́ sí oúnjẹ náà, tá a pè ní Voucher ti ń wáyé lọ́wọ́ nílùú Àbújá àti Èkó, tí Ìjọba sì ti ń pèsè owó fún àwọn Ìjọba Ìpínlẹ̀ láti sètò ìpèsè oúńjẹ fún akẹ́kọ́ọ̀ nípìnlẹ̀ kóówá wọn.”