Home / Art / Àṣà Oòduà / Won gun pasito ijo RCCG lobe niluu Ota
redeem

Won gun pasito ijo RCCG lobe niluu Ota

Edward Campbell, eni odun mokandinlaadota (49) ni won ti gbe lo si ile ejo lojo Eti to koja yii pelu esun wi pe o gun pasito Redeemed Christian Church of God (RCCG), Dotun Olojede, lo be.

Ile ejo Majisireeti to gaju lo to wa l’Ota nipinle Ogun ni asoju ileese olopaa, Sajenti Chudu Gbesi ti gbe n salaye fun ile ejo wi pe, ojo kejo osu kokanla odun yii ni Edward fi obe gun pasito ni ile ijosin RCCG, eka Fruitful Vine Parish to wa ni Ilo Awera niluu Ota.

Igba ti won yoo ma pe Edward jade lati se alaye tenu re bi isele naa se waye, oro re ko po rara. “Oluwa mi, mi o jebi esun ti won fi kan mi” ni soki oro to jade lenu re.
Onidajo, ogbeni S.O Banwo ni ki won gba beeli re pelu egberun lona aadota owo naira (N50,000) pelu oniduro to lokun nidi to si rese wale daada. Oniduro naa si gbodo se afihan eri owo ori sisan lati nnkan bi odun meji seyin ati foto pelebe tuntun ti won seseya
Leyin eyi ni onidajo sun ejo naa siwaju lati faaye sile fun iwadii to jinle saaju ki won to mo ibi ti won yoo da ejo naa si. Ojo kerin, osu kejila odun yii ni won yoo tun maa gbe igbejo naa dide lakotun.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti