Leyin odun marun-un ti ijoba ipinle Ondo ro Adesina Adepoju loye gege bi Deji tilu Akure, oba ilu Akure nigba kan ri naa ti gbe ejo dide ni kootu lati gba ade re pada.
Ojo kewaa osu kefa odun 2010 ni ijoba ipinle Ondo yo Adepoju loye gege bi oba ilu Akure latari bo se ran awon janduku lati lo na iyawo re, oloogbe Bolanle Adepoju.
Ojo Isegun to koja yii ni awon eniyan ilu Akure bere si ni ko okan won soke nigba ti won gbo wi pe Ogbeni Adepoju ti won ti ni ko gbodo wo ilu Akure mo ti wa ni ile ejo to gaju niluu Akure lati gba ade re pada.
Agbejoro olupejo, Barisita Olelekan Ojo so niwaju adajo wi pe ona ti ko to ni won gba yo onibara re, Ogbeni Adepoju loye gege bi Deji tilu Akure. O si n ro ile ejo lati pase wi pe ki won da ipo oba naa pada fun Adepoju eni to fi ilu oyinbo sele nikete ti won gba ade lori re lodun 2010.
Gbogbo ara idile Osupa, to je okan lara awon idile ti n joba niluu Akure ni won dide lati koworin pelu Adepoju lo sile ejo. Aimoye ore, ojulumo, alatileyin re naa peju lati teti sibi ti ejo naa yoo yori si.
Lopin ohun gbogbo, Adajo Agba Olaseinde Kumuyi sun igbejo naa siwaju di ojo kejo osu kejila odun yii (08/12/2015) nigba ti ile ejo yoo tun maa pada joko lori oro naa.
Tijo-tilu-tifon ni awon ebi Adepoju fi sin omo won pada sile lati kootu pelu ogooro awon olopaa ti won yi won ka.
Leyin ti won yo Adepoju loye ni Oba Adebiyi Adesida gori oye gege bi oba eleekerindinlaadota (46th) ti yoo je niluu Akure Oloyemekun. Leyin ti oba yii gbese ni omo re obirin dele titi ti won fi fi Oba Aladetoyinbo joba.
Bi o tile je wi pe Adepoju ja raburabu ni akoko ti won fe yan oba tuntun naa lati di Deji leyin iku Oba Adesida, sugbon gbogbo igbiyanju re nigba naa lo ja sori ofo.
Awuyewuye kan tile tun gba igboro Akure kan-an lojo Isegun nigba ti Adepoju fara han fun igba akoko leyin ti won ti le niluu naa wi pe gbaga awon olopaa ni yoo sun lale ojo naa.
Sugbon gege bi oro agbenuso fun ile ise olopaa ipinle naa, Ogbeni Femi Joseph, so wi pe Adepoju ko se ese kankan loju awon to le mu awon ti i mole.
“Bi awon olopaa se lo pade Adepoju ni kootu ati bi won se tele dele kii se lati lo gbe e timole, bi ko se lati daabo bo emi ati dukia awon eniyan lapapo. Ojuse tiwa ni lati ma je ki awon omo janduku lo anfaani naa lati da alafia ilu laamu”, Ogbeni Joseph fi kun oro re bee.
Gege bi itan atenudenu se so, Odun 1150 AD ni won da ilu Akure sile lati owo Omoremi Omoluabi to je omoomo bibi inu Odudua Ateworan. Awon oloye agba mefa ni won maa sise pelu Deji Akure lati dari ilu naa, awon oloye mefa naa si ni a mo si Iwarefa. Ilu Akure ni olu ilu Ipinle Ondo, ibe naa si tun ni ibujoko ijoba ipinle naa.