Home / Art / Àṣà Oòduà / “Kosi ona ti a fe gbegba, ijoba ni lati yo owo iranwo ori epo kuro” – Oyegun

“Kosi ona ti a fe gbegba, ijoba ni lati yo owo iranwo ori epo kuro” – Oyegun

Alaga egbe oselu APC, oloye John Odigie-Oyegun ti fi da awon omo Naijiria loju wi pe, kosi ipadaseyin ninu yiyo owo iranwo ori epo robi.

Oyegun lo n soro yii nigba ti n gbalejo awon iko kan lati inu egbe oselu APC, APC National Coalition for Peace and Mobilization (NACOPEAM).

Gege bi oro re, jegudujera ati aitele awon ilana to ye eleyii ti ijoba Goodluck Jonathan faaye gba se opolopo akoba fun eto oro-aje ati isejoba Naijiria.

Bakan naa lo fi kun wi pe, awon nnkan to ti baje labenu yii ko je ki isejoba rorun fun Aare Muhammadu Buhari.

Yato si eleyii, awon arijenimadaru ti won ti tojubo epo robi ko je ki owo ti ijoba nla lori iranwo epo o funa. Awon eniyan yii kan naa ni won si n se agbateru igbogun ti ijoba lati ma yowo iranwo ori epo kuro.

“Ona abayo kankan soso lati tete da ogo oro aje Naijiria pada ni yiyo owo iranwo ori epo kuro. Idi pataki ti ijoba fi gbodo se eleyii gbodo ye omo Naijiria pata.

Ohun ti ijoba Buhari ba nile ko mu isakoso Naijiria rorun fun-un. Ti a ko ba si se awon nnkan woyii ni akoko to ye, ifaseyin le de ba awon ileri ti a se fun awon ara ilu ni akoko ipolongo,” Oyegun se lalaye bee

Bakan naa ni Oloye Oyegun n ro awon ara ilu lati fowosowopo pelu ijoba to wa lode yii ki awon erogba re pata le kesejari.

About admin

One comment

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

balogun ilu yoruba

Remembering Famous Balogun (Generals) of Yoruba Land.

1) Balogun Oderinlo of Ibadan – Conquered the Fulanis in Osogbo.2) Balogun Ibikunle of Ibadan – defeated the treacherous Aare Ona Kakanfo Kurumi of Ijaye.3) Balogun Akere of Ibadan – died while fighting against the Ijesha army in the Kiriji war.4) Balogun Orowusi of Ibadan – defeated the Ijesha army.5) Balogun Ogunbona of Egba land – conquered the Dahomey army.6) Balogun Osungboekun of Ibadan – replaced Latoosa in the Ekiti Parapo/Kiriji war.7) Balogun Olasile of Ijaye – served and died ...