Home / Art / Àṣà Oòduà / Owo awon olopaa te ole ajipata ati komu niluu Ibadan
police

Owo awon olopaa te ole ajipata ati komu niluu Ibadan

Ero o gbese ni olu ile ise awon olopaa ipinle Oyo to wa ni Eleyele nigba ti won se afihan awon igara olosa ajipata ati komu gbe fun awon oniroyin niluu Ibadan.

Awon ole bi merin yii lagbo wi pe won lo fo soobu ti won ti n ta awotele awon obirin loru Ojobo mojumo ojo Eti to koja yii ni agbegbe Sango to wa niluu Ibadan.

Leyin ise buruku owo won, awon figilante adugbo naa to ipase won lo si ibuba won to wa ni agbegbe Apete ni ijoba ibile Ido, ko to di wi pe won fa won le awon agbofinro lowo.

Bolanle Ogunmiye, onisowo ti awon ole naa ja soobu re ti bere si ni bu omi ope mu fun komisanna awon olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adeleye Oyebade fun iranwo ti won se lati ri awon ole naa mu.

Ile ise olopaa ipinle naa si fi da awon oniroyin loju wi pe awon ole naa ko ni i foju bale ejo lati lo foju wina ise owo won.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti