Owo te awon igara olosa meji kan ti won fi okada jawo gba loju opopona IBB to wa ni agbegbe Maitama niluu Abuja lojo Tuside to koja yii.
Ile ifowopamo kan to wa ni opopona IBB ni enikan to je onibara banki naa ti jade pelu owo tabua to lo gba ninu baagi.
Ki maanu to gbe baagi dani naa to seju pe, awon alokolounkigbe ti koja mo o lara, won ja baagi re gba bee ni okunrin oni baagi ba figbe ta, “ole” “ole” “ole.”
Awon ara agbegbe naa jigiri si igbe ariwo ole ti won pa lesekese, eleyii lo sokunfa bi owo se te awon ole naa.
Awon Yoruba ni ojo gbogbo ni tole, ojo kan pere ni toloun. Awon eniyan ko tile duro de olopaa alaso dudu ki won to bere si se idajo owo won fun awon ole naa. Won fo won ni kondo lenu, awon kan jin won lese leyin orun. Awon kan ni e lo gbe taya wa, e je ka sun won bi suya alata suesue.