Home / Art / Àṣà Oòduà / Àwàdà kẹrí-Kẹrì ni àwọn kọmití tó ní mi ò lè díje du ipò gómìnà APC ni 2026 n ṣe – Omisore
Omisore

Àwàdà kẹrí-Kẹrì ni àwọn kọmití tó ní mi ò lè díje du ipò gómìnà APC ni 2026 n ṣe – Omisore

Yínká Àlàbí

Awọn kọmiti to n ṣe àyẹ̀wò awọn oludije du ipo gomina labẹ ẹgbẹ́ oselu APC ti ja igbakeji gomina tẹlẹ ni ipinle Osun, Alagba Iyiola Omisore ati awọn mẹfa miiran.
Wọn ni iwe wọn ko pe lati dije du ipo gomina ipinlẹ naa. Awọn mẹfẹẹfa to ku naa ni – Babatunde Oralusi, Oyedotun Babayemi, Dr. Akin Ogunbiyi, Benedict Alabi, Adegoke Rasheed Okiki, ati Senator Babajide Omoworare.

Iyiola Omisore ni awada Kẹri-Kẹri ni awọn kọmiti naa n se nitori ti wọn ba gbe ofin kankan dide, gbogbo awọn oludije lo maa mu ti ko ba lọwọ aye ninu.
Omisore tun ni oun funra si gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola pe o lọwọ si bi wọn se ni oun ja kulẹ ninu idije naa. O ni ọta ẹni o ki n pa odu ọya ni oun ati Oyetola.
Awọn kọmiti ni Munirudeen Bola Oyebamiji ati Mulikat Abiola Jimoh lo kun oju osuwọn lati dije ni ọjọ kẹtala, osu kejila ọdun yii ki wọn to wa mu enikan to maa soju ẹgbẹ oselu APC ni ọdun to n bọ.
Awọn kọmiti naa da Omisore lohun pe ofin ẹgbẹ tó wa ni abala 9.3(i) ati 31.2(ii) ati Paragraph 6(c) ti ẹgbẹ́ là kalẹ̀ ni àwọn tẹ̀lé.

Orisun

About ayangalu

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

yemoja 2026

Yoruba Yemoja float with 10,000 Litres of water by Mocidade Alegre Won the São Paulo Carnival 2026 in Brazil!

This majestic allegorical float, a viral sensation during the parade, featured Yemoja (Iemanjá) Yemoja was powerfully incorporated because the enredo “Malunga Léa – Rapsódia de uma Deusa Negra” was a heartfelt tribute to the late legendary Brazilian actress Léa Garcia (1930–2023). A pioneering African icon in theater, film, and TV (famous for roles like in Escrava Isaura and her work with Teatro Experimental do Negro). The theme celebrated her as a “deusa negra” (“Black” Goddess): her resilience, ancestral strength, female ...